OLUWA Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgbà Edeni lati ma ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ. OLUWA Ọlọrun si fi aṣẹ fun ọkunrin na pe, Ninu gbogbo igi ọgbà ni ki iwọ ki o ma jẹ: Ṣugbọn ninu igi ìmọ rere ati bururu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀: nitoripe li ọjọ́ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kikú ni iwọ o kú. OLUWA Ọlọrun si wipe, kò dara ki ọkunrin na ki o nikan ma gbé; emi o ṣe oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wò orukọ ti yio sọ wọn; orukọkorukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda alãye, on li orukọ rẹ̀. Adamu si sọ ẹran-ọ̀sin gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko igbẹ gbogbo, li orukọ; ṣugbọn fun Adamu a kò ri oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u.
Kà Gẹn 2
Feti si Gẹn 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 2:15-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò