Gẹn 2:1-15

Gẹn 2:1-15 YBCV

BẸ li a pari ọrun on aiye, ati gbogbo ogun wọn. Ni ijọ́ keje Ọlọrun si pari iṣẹ rẹ̀ ti o ti nṣe; o si simi ni ijọ́ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti nṣe. Ọlọrun si busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́; nitori pe, ninu rẹ̀ li o simi kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti bẹ̀rẹ si iṣe. Itan ọrun on aiye ni wọnyi nigbati a dá wọn, li ọjọ́ ti OLUWA Ọlọrun dá aiye on ọrun. Ati olukuluku igi igbẹ ki o to wà ni ilẹ, ati olukuluku eweko igbẹ ki nwọn ki o to hù: OLUWA Ọlọrun kò sa ti rọ̀jo si ilẹ, kò si sí enia kan lati ro ilẹ. Ṣugbọn ikũku a ti ilẹ wá, a si ma rin oju ilẹ gbogbo. OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn. OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu. Odò kan si ti Edeni ṣàn wá lati rin ọgbà na; lati ibẹ̀ li o gbé yà, o si di ipa ori mẹrin. Orukọ ekini ni Pisoni: on li eyiti o yi gbogbo ilẹ Hafila ká, nibiti wurà wà; Wurà ilẹ na si dara: nibẹ ni bedeliumu (ojia) wà ati okuta oniki. Orukọ odò keji si ni Gihoni: on na li eyiti o yi gbogbo ilẹ Kuṣi ká. Ati orukọ odò kẹta ni Hiddekeli: on li eyiti nṣàn lọ si ìha ìla-õrùn Assiria. Ati odò kẹrin ni Euferate. OLUWA Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgbà Edeni lati ma ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa