Gẹn 16:1-6

Gẹn 16:1-6 YBCV

SARAI, aya Abramu, kò bímọ fun u: ṣugbọn o li ọmọ-ọdọ kan obinrin, ara Egipti, orukọ ẹniti ijẹ Hagari. Sarai si wi fun Abramu pe, kiyesi i na, OLUWA dá mi duro lati bímọ: emi bẹ̀ ọ, wọle tọ̀ ọmọbinrin ọdọ mi; o le ṣepe bọya emi a ti ipasẹ rẹ̀ li ọmọ. Abramu si gbà ohùn Sarai gbọ́. Sarai, aya Abramu, si mu Hagari ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ ara Egipti na, lẹhin igbati Abramu gbé ilẹ Kenaani li ọdún mẹwa, o si fi i fun Abramu ọkọ rẹ̀ lati ma ṣe aya rẹ̀. On si wọle tọ̀ Hagari, o si loyun: nigbati o ri pe on loyun, oluwa rẹ̀ obinrin wa di ẹ̀gan li oju rẹ̀. Sarai si wi fun Abramu pe, Ẹbi mi wà lori rẹ: emi li o fi ọmọbinrin ọdọ mi fun ọ li àiya; nigbati o si ri pe on loyun, mo di ẹ̀gan li oju rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe idajọ lãrin temi tirẹ. Ṣugbọn Abramu wi fun Sarai pe, Wò o, ọmọbinrin ọdọ rẹ wà li ọwọ́ rẹ: fi i ṣe bi o ti tọ́ li oju rẹ. Nigbati Sarai nfõró rẹ̀, o sá lọ kuro lọdọ rẹ̀.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gẹn 16:1-6