GBOGBO aiye si jẹ ède kan, ati ọ̀rọ kan. O si ṣe, bi nwọn ti nrìn lati ìha ìla-õrùn lọ, ti nwọn ri pẹtẹlẹ kan ni ilẹ Ṣinari; nwọn si tẹdo sibẹ̀. Nwọn si wi, ikini si ekeji pe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a mọ briki, ki a si sun wọn jina. Briki ni nwọn ni li okuta, ọ̀da-ilẹ ni nwọn si nfi ṣe ọ̀rọ. Nwọn si wipe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a tẹ̀ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyiti yio si kàn ọrun; ki a si li orukọ, ki a má ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo. OLUWA si sọkalẹ wá iwò ilu ati ile-iṣọ́ na, ti awọn ọmọ enia nkọ́. OLUWA si wipe, Kiye si i, ọkan li awọn enia, ède kan ni gbogbo wọn ni; eyi ni nwọn bẹ̀rẹ si iṣe: njẹ nisisiyi kò sí ohun ti a o le igbà lọwọ wọn ti nwọn ti rò lati ṣe. Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a sọkalẹ lọ, ki a dà wọn li ède rú nibẹ̀, ki nwọn ki o máṣe gbedè ara wọn mọ́. Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Babeli; nitori ibẹ̀ li OLUWA gbe dà ède araiye rú, lati ibẹ̀ lọ OLUWA si tú wọn ká kiri si ori ilẹ gbogbo.
Kà Gẹn 11
Feti si Gẹn 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 11:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò