Ṣugbọn ki igbagbọ́ to de, a ti pa wa mọ́ labẹ ofin, a si sé wa mọ́ de igbagbọ́ ti a mbọwa fihàn. Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ́. Ṣugbọn lẹhin igbati igbagbọ́ ti de, awa kò si labẹ olukọni mọ́. Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. Nitoripe iye ẹnyin ti a ti baptisi sinu Kristi, ti gbe Kristi wọ̀. Kò le si Ju tabi Hellene, ẹrú tabi omnira, ọkunrin tabi obinrin: nitoripe ọ̀kan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu. Bi ẹnyin ba si jẹ ti Kristi, njẹ ẹnyin ni irú-ọmọ Abrahamu, ati arole gẹgẹ bi ileri.
Kà Gal 3
Feti si Gal 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gal 3:23-29
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò