Esr 2

2
Àwọn tí Wọ́n Pada ti Ìgbèkùn Dé
(Neh 7:4-73)
1WỌNYI li awọn ọmọ igberiko Juda ti o goke wa, lati inu igbèkun awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnessari, ọba Babiloni, ti ko lọ si Babiloni, ti nwọn si pada wá si Jerusalemu ati Juda, olukuluku si ilu rẹ̀:
2Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin ninu awọn enia Israeli:
3Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbọkanla o din mejidilọgbọn.
4Awọn ọmọ Ṣefatiah, irinwo o din mejidilọgbọn.
5Awọn ọmọ Ara, ẹgbẹrin o din mẹ̃dọgbọn.
6Awọn ọmọ Pahati-Moabu ninu awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejila.
7Awọn ọmọ Elamu, adọtalelẹgbẹfa o le mẹrin.
8Awọn ọmọ Sattu, ọtadilẹgbẹ̀run, o le marun.
9Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin.
10Awọn ọmọ Bani, ojilelẹgbẹta, o le meji.
11Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mẹtalelogun.
12Awọn ọmọ Asgadi, ẹgbẹfa, o le mejilelogun.
13Awọn ọmọ Adonikami ọtalelẹgbẹta o le mẹfa.
14Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹrindilọgọta.
15Awọn ọmọ Adini, adọtalenirinwo o le mẹrin.
16Awọn ọmọ Ateri ti Hesekiah, mejidilọgọrun.
17Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹta.
18Awọn ọmọ Jora, mejilelãdọfa.
19Awọn ọmọ Haṣumu igba o le mẹtalelogun.
20Awọn ọmọ Gibbari, marundilọgọrun.
21Awọn ọmọ Betlehemu, mẹtalelọgọfa.
22Awọn enia Netofa, mẹrindilọgọta.
23Awọn enia Anatotu, mejidilãdọje.
24Awọn ọmọ Asmafeti, mejilelogoji.
25Awọn ọmọ Kirjat-arimu, Kefira ati Beeroti ọtadilẹgbẹrin o le mẹta.
26Awọn ọmọ Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun.
27Awọn ọmọ Mikmasi, mejilelọgọfa.
28Awọn enia Beteli ati Ai, igba o le mẹtalelogun.
29Awọn ọmọ Nebo, mejilelãdọta.
30Awọn ọmọ Magbiṣi mẹrindilọgọjọ.
31Awọn ọmọ Elamu ekeji, ãdọtalelẹgbẹfa o le mẹrin.
32Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.
33Awọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le marun,
34Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.
35Awọn ọmọ Sanaa, egbejidilogun o le ọgbọn.
36Awọn alufa; awọn ọmọ Jedaiah, ti idile Jeṣua, ogúndilẹgbẹrun o din meje.
37Awọn ọmọ Immeri, ãdọtalelẹgbẹrun o le meji.
38Awọn ọmọ Paṣuri, ojilelẹgbẹfa o le meje.
39Awọn ọmọ Harimu, ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.
40Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua ati Kadmieli ti awọn ọmọ Hodafiah, mẹrinlelãdọrin.
41Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdoje.
42Awọn ọmọ awọn adena: awọn ọmọ Ṣalumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, gbogbo wọn jẹ, mọkandilogoje.
43Awọn Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Hasufa, awọn ọmọ Tabbaoti.
44Awọn ọmọ Kerosi, awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Padoni.
45Awọn ọmọ Lebana, awọn ọmọ Hagaba, awọn ọmọ Akkubu,
46Awọn ọmọ Hagabu, awọn ọmọ Ṣalmai, awọn ọmọ Hanani;
47Awọn ọmọ Giddeli, awọn ọmọ Gahari, awọn ọmọ Reaiah,
48Awọn ọmọ Resini, awọn ọmọ Nekoda, awọn ọmọ Gassamu,
49Awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Pasea, awọn ọmọ Besai,
50Awọn ọmọ Asna, awọn ọmọ Mehunimi, awọn ọmọ Nefusimi,
51Awọn ọmọ Bakbuki, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Har-huri,
52Awọn ọmọ Basluti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harṣa,
53Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama,
54Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa,
55Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Peruda,
56Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli,
57Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Ami.
58Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni, jẹ irinwo o din mẹjọ.
59Awọn wọnyi li o si goke wá lati Telmela, Telkarsa, Kerubu, Addani, ati Immeri: ṣugbọn nwọn kò le fi idile baba wọn hàn, ati iru ọmọ wọn, bi ti inu Israeli ni nwọn iṣe:
60Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ãdọtalelẹgbẹta o le meji.
61Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Hakosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o fẹ ọkan ninu awọn ọmọ Barsillai obinrin, ara Gileadi li aya, a si pè e nipa orukọ wọn;
62Awọn wọnyi li o wá iwe itan wọn ninu awọn ti a ṣiro nipa itan idile, ṣugbọn a kò ri wọn, nitori na li a ṣe yọ wọn kuro ninu oye alufa.
63Balẹ si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o má jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi dide pẹlu Urimu ati pẹlu Tummimu.
64Apapọ gbogbo ijọ na, jẹ ẹgbã mọkanlelogun o le ojidinirinwo.
65Li aika iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹbinrin wọn, ti o jẹ ẹgbẹrindilẹgbãrin o din mẹtalelọgọta: igba akọrin ọkunrin ati akọrin obinrin li o si wà ninu wọn.
66Ẹṣin wọn jẹ, ọtadilẹgbẹrin o din mẹrin; ibaka wọn, ojilugba o le marun.
67Ibakasiẹ wọn, irinwo o le marundilogoji; kẹtẹkẹtẹ wọn, ẹgbẹrinlelọgbọn o din ọgọrin.
68Ati ninu awọn olori awọn baba, nigbati nwọn de ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu, nwọn si ta ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun, lati gbe e duro ni ipò rẹ̀.
69Nwọn fi sinu iṣura iṣẹ na gẹgẹ bi agbara wọn, ọkẹ mẹta ìwọn dramu wura, o le ẹgbẹrun, ẹgbẹdọgbọn mina fadaka, ati ọgọrun ẹ̀wu alufa.
70Bẹ̃li awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati omiran ninu awọn enia, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, ati awọn Netinimu ngbe ilu wọn, gbogbo Israeli si ngbe ilu wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esr 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀