NIGBATI Esra ti gba adura, ti o si jẹwọ pẹlu ẹkún ati idojubolẹ niwaju ile Ọlọrun, ijọ enia pupọ kó ara wọn jọ si ọdọ rẹ̀ lati inu Israeli jade, ati ọkunrin ati obinrin ati ọmọ wẹwẹ: nitori awọn enia na sọkun gidigidi.
Ṣekaniah ọmọ Jehieli, lati inu awọn ọmọ Elamu dahùn o si wi fun Esra pe, Awa ti ṣẹ̀ si Ọlọrun wa, ti awa ti mu ajeji obinrin lati inu awọn enia ilẹ na: sibẹ, ireti mbẹ fun Israeli nipa nkan yi.
Njẹ nitorina ẹ jẹ ki awa ki o ba Ọlọrun wa da majẹmu, lati kọ̀ gbogbo awọn obinrin na silẹ, ati iru awọn ti nwọn bi gẹgẹ bi ìmọ (Esra) oluwa mi, ati ti awọn ti o wariri si aṣẹ Ọlọrun wa: ki awa ki o si mu u ṣẹ gẹgẹ bi ofin na.
Dide! nitori ọran tirẹ li eyi: awa pãpã yio wà pẹlu rẹ, mu ọkàn le ki o si ṣe e.
Esra si dide, o si mu awọn olori ninu awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Israeli bura pe, awọn o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Nwọn si bura.
Esra si dide kuro niwaju ile Ọlọrun, o si wọ̀ yara Johanani ọmọ Eliaṣibu lọ: nigbati o si lọ si ibẹ, on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi: nitoripe o nṣọ̀fọ nitori irekọja awọn ti a kó lọ.
Nwọn si kede ja gbogbo Juda ati Jerusalemu fun gbogbo awọn ọmọ igbèkun, ki nwọn ki o kó ara wọn jọ pọ̀ si Jerusalemu;
Ati pe ẹnikẹni ti kò ba wá niwọ̀n ijọ mẹta, gẹgẹ bi ìmọ awọn olori ati awọn agba, gbogbo ini rẹ̀ li a o jẹ, on tikararẹ̀ li a o si yà kuro ninu ijọ awọn enia ti a ti ko lọ.
Nitori eyi ni gbogbo awọn enia Juda ati Benjamini ko ara wọn jọ pọ̀ ni ọjọ mẹta si Jerusalemu, li oṣu kẹsan, li ogun ọjọ oṣu; gbogbo awọn enia si joko ni ita ile Ọlọrun ni iwarìri nitori ọ̀ran yi, ati nitori òjo-pupọ.
Nigbana ni Esra alufa dide duro, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣẹ̀, ẹnyin ti mu àjeji obinrin ba nyin gbe lati sọ ẹ̀ṣẹ Israeli di pupọ,
Njẹ nitorina, ẹ jẹwọ fun Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin, ki ẹnyin ki o si mu ifẹ rẹ̀ ṣẹ; ki ẹnyin ki o si ya ara nyin kuro ninu awọn enia ilẹ na, ati kuro lọdọ awọn ajeji obinrin.
Nigbana ni gbogbo ijọ enia na dahùn, nwọn si wi li ohùn rara pe, Bi iwọ ti wi, bẹ̃ni awa o ṣe.
Ṣugbọn awọn enia pọ̀, igba òjo pupọ si ni, awa kò si le duro nita, bẹ̃ni eyi kì iṣe iṣẹ ọjọ kan tabi meji: nitoriti awa ti ṣẹ̀ pupọpupọ ninu ọ̀ran yi.
Njẹ ki awọn olori wa ki o duro fun gbogbo ijọ enia, ki a si jẹ ki olukuluku ninu ilu wa ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe, ki o wá ni wakati ti a da, ati awọn olori olukuluku ilu pẹlu wọn, ati awọn onidajọ wọn, titi a o fi yi ibinu kikan Ọlọrun wa pada kuro lọdọ wa nitori ọ̀ran yi.
Sibẹ Jonatani ọmọ Asaheli, ati Jahasiah ọmọ Tikfa li o dide si eyi, Meṣullamu ati Ṣabbetai, ọmọ Lefi, si ràn wọn lọwọ.
Ṣugbọn awọn ọmọ igbekun ṣe bẹ̃. Ati Esra, alufa, pẹlu awọn olori ninu awọn baba, nipa ile baba wọn, ati gbogbo wọn nipa orukọ wọn li a yà si ọ̀tọ, ti nwọn si joko li ọjọ kini oṣu kẹwa, lati wadi ọ̀ran na.
Nwọn si ba gbogbo awọn ọkunrin ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe ṣe aṣepari, li ọjọ ekini oṣu ekini.
Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa, a ri awọn ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe: ninu awọn ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati awọn arakunrin rẹ̀; Maaseiah, ati Elieseri, ati Jaribi ati Gedaliah.
Nwọn si fi ọwọ wọn fun mi pe: awọn o kọ̀ awọn obinrin wọn silẹ; nwọn si fi àgbo kan rubọ ẹ̀ṣẹ nitori ẹbi wọn.
Ati ninu awọn ọmọ Immeri; Hanani ati Sebadiah.
Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Maaseiah, ati Elija, ati Ṣemaiah, ati Jehieli, ati Ussiah.
Ati ninu awọn ọmọ Paṣuri; Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Nataneeli Josabadi, ati Eleasa.
Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Josabadi, ati Ṣimei, ati Kelaiah (eyi ni Kelita) Petahiah, Juda, ati Elieseri.
Ninu awọn akọrin pẹlu; Eliaṣibu: ati ninu awọn adèna; Ṣallumu, ati Telemi, ati Uri.
Pẹlupẹlu ninu Israeli: ninu awọn ọmọ Paroṣi: Ramiah, ati Jesiah, ati Malkiah, ati Miamini, ati Eleasari, ati Malkijah, ati Benaiah.
Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Mattaniah, Sekariah, ati Jehieli, ati Abdi, ati Jeremoti, ati Elijah.
Ati ninu awọn ọmọ Sattu; Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, ati Jeremoti, ati Sabadi, ati Asisa.
Ninu awọn ọmọ Bebai pẹlu; Jehohanani, Hananiah, Sabbai ati Atlai.
Ati ninu awọn ọmọ Bani; Meṣullamu, Malluki, ati Adaiah, Jaṣubu, ati Ṣeali ati Ramoti.
Ati ninu awọn ọmọ Pahat-moabu Adma ati Kelali, Benaiah, Maaseiah, Mattaniah, Besaleeli, ati Binnui, ati Manasse.
Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Elieseri, Isṣjah, Malkiah, Ṣemaiah, Ṣimeoni,
Benjamini, Malluki, ati Ṣemariah.
Ninu awọn ọmọ Haṣumu; Mattenai, Mattatta, Sabadi, Elifeleti, Jeremai, Manasse, ati Ṣimei.
Ninu awọn ọmọ Bani; Maadai, Amramu ati Ueli.
Benaiah, Bedeiah, Kellu,
Faniah, Meremoti, Eliaṣibu,
Mattaniah, Mattenai ati Jaasau,
Ati Bani, ati Binnui, Ṣimei.
Ati Ṣelemiah, ati Natani, ati Adaiah,
Maknadebai, Saṣai, Ṣarai,
Asareeli, ati Ṣelemiah, Ṣemariah.
Ṣallumu, Amariah, ati Josefu.
Ninu awọn ọmọ Nebo; Jeieli, Mattitiah, Sabadi, Ṣebina, Jadau, ati Joeli, Benaiah.
Gbogbo awọn yi li o mu ajeji obinrin ba wọn gbe, omiran ninu wọn si ni obinrin nipa ẹniti nwọn li ọmọ.