Esek 6
6
Ọlọrun fi Ìbọ̀rìṣà Gégùn-ún
1Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, kọju rẹ si awọn oke-nla Israeli, si sọtẹlẹ si wọn.
3Si wipe, Ẹnyin oke-nla Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; bayi li Oluwa Ọlọrun wi si awọn oke-nla, si awọn oke kekeke, si awọn odò siṣàn, ati si awọn afonifoji; kiyesi i, Emi, ani Emi, o mu idà wá sori nyin, emi o si pa ibi giga nyin run.
4Pẹpẹ nyin yio si di ahoro, ere nyin yio si fọ; okú nyin li emi o si gbe jù siwaju oriṣa nyin.
5Emi o si tẹ́ okú awọn ọmọ Israeli siwaju oriṣa wọn; emi o si tú egungun nyin ka yi pẹpẹ nyin ka.
6Ilu-nla li a o parun ninu gbogbo ibugbe nyin, ibi giga yio si di ahoro: ki a le run pẹpẹ nyin, ki a si sọ ọ di ahoro, ki a si le fọ́ oriṣa nyin, ki o si tan, ki a si le ké ere nyin lu ilẹ, ki iṣẹ́ nyin si le parẹ.
7Okú yio si ṣubu li ãrin nyin, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.
8Ṣugbọn emi o fi iyokú silẹ, ki ẹnyin le ni diẹ ti yio bọ́ lọwọ idà lãrin awọn orilẹ-ède, nigbati a o tú nyin ka gbogbo ilẹ.
9Awọn ti o bọ́ ninu nyin yio si ranti mi, lãrin awọn orilẹ-ède nibiti nwọn o gbe dì wọn ni igbekun lọ, nitoriti mo ti fọ́ ọkàn agbere wọn ti o ti lọ kuro lọdọ mi, ati pẹlu oju wọn, ti nṣagbere lọ sọdọ oriṣa wọn: nwọn o si sú ara wọn nitori ìwa ibi ti nwọn ti hù ninu gbogbo irira wọn.
10Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, emi kò wi lasan pe, emi o ṣe ibi yi si wọn.
11Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pàtẹwọ rẹ, si fi ẹsẹ rẹ kì ilẹ; si wipe, o ṣe! fun gbogbo irira buburu ilẹ Israeli, nitori nwọn o ṣubu nipa idà, nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ àrun.
12Ẹniti o jina rere yio kú nipa ajakalẹ àrun; ati ẹniti o sunmọ tosí yio ṣubu nipa idà; ati ẹniti o kù ti a si do tì yio kú nipa iyàn: bayi li emi o mu irunu mi ṣẹ lori wọn.
13Nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati okú wọn yio wà larin ere wọn yi pẹpẹ wọn ka, lori oke kekeke gbogbo, lori ṣonṣo ori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo, ati labẹ gbogbo igi oaku bibò, ibiti nwọn ti rubọ õrùn didùn si gbogbo ere wọn.
14Bẹ̃ li emi o nà ọwọ́ mi jade sori wọn, emi o si sọ ilẹ na di ahoro, nitotọ, yio di ahoro jù aginju iha Diblati lọ, ninu gbogbo ibugbe wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esek 6: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.