Ati ipín kan yio jẹ ti olori nihà kan ati niha keji ọrẹ ipin mimọ́, ati ti ini ilu, ti o kọju si ọrẹ ipín mimọ́, ti o si kọju si iní ti ilu, lati iha iwọ-õrun si iwọ-õrun, ati lati ihà ila-õrun si ila-õrun: gigùn rẹ̀ yio gbe ọkan ninu awọn ipín, lati eti iwọ-õrun de eti ila-õrun. Ni ilẹ na ni iní rẹ̀ yio wà ni Israeli: awọn olori mi kì yio si ni awọn enia mi lara mọ́; ati ilẹ iyokù ni nwọn o fi fun ile Israeli gẹgẹ bi ẹyà wọn. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ki o to fun nyin, ẹnyin olori Israeli: ẹ mu ìwa ipa irẹ́jẹ kuro, ki ẹ si mu idajọ ati ododo ṣẹ, mu ilọ́nilọwọgbà nyin kuro lọdọ awọn enia mi, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ki ẹnyin ki o ni ìwọn títọ, ati efà títọ, ati bati títọ. Efa ati bati yio jẹ ìwọn kanna, ki bati ba le gbà ìdamẹwa homeri, ati efa idamẹwa homeri: iwọ̀n rẹ̀ yio jẹ gẹgẹ bi ti homeri. Ṣekeli yio si jẹ́ ogún gera: ogún ṣekeli, ṣekeli mẹdọgbọ̀n, ṣekeli mẹdogun, ni manẹ nyin yio jẹ.
Kà Esek 45
Feti si Esek 45
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Esek 45:7-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò