Nigbana li o sọ fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi ni gbogbo ile Israeli: wò o, nwọn wipe, Egungun wa gbẹ, ireti wa si pin: ni ti awa, a ti ke wa kuro. Nitorina sọtẹlẹ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, ẹnyin enia mi, emi o ṣi ibojì nyin, emi o si mu ki ẹ dide kuro ninu ibojì nyin, emi o si mu nyin wá si ilẹ Israeli. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi bá ti ṣí ibojì nyin, ẹnyin enia mi, ti emi bá si mu nyin dide kuro ninu ibojì nyin. Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, ẹnyin o si yè, emi o si mu nyin joko ni ilẹ ti nyin: nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ ọ, ti o si ti ṣe e, li Oluwa wi.
Kà Esek 37
Feti si Esek 37
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Esek 37:11-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò