ỌWỌ́ Oluwa wà li ara mi, o si mu mi jade ninu ẹmi Oluwa, o si gbe mi kalẹ li ãrin afonifojì ti o kún fun egungun,
O si mu mi rìn yi wọn ka: si wò o, ọ̀pọlọpọ ni mbẹ ni gbangba afonifojì; si kiyesi i, nwọn gbẹ pupọpupọ.
O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi le yè? Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ li o le mọ̀.
O tun wi fun mi pe, Sọtẹlẹ sori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, Ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa.
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun egungun wọnyi; Kiyesi i, emi o mu ki ẽmi wọ̀ inu nyin, ẹnyin o si yè:
Emi o si fi iṣan sara nyin, emi o si mu ẹran wá sara nyin, emi o si fi àwọ bò nyin, emi o si fi ẽmi sinu nyin, ẹnyin o si yè; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Bẹ̃ni mo ṣotẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi: bi mo si ti sọtẹlẹ, ariwo ta, si wò o, mimì kan wà, awọn egungun na si wá ọdọ ara wọn, egungun si egungun rẹ̀.
Nigbati mo si wò, kiyesi i, iṣan ati ẹran-ara wá si wọn, àwọ si bò wọn loke: ṣugbọn ẽmi kò si ninu wọn.
Nigbana li o sọ fun mi, pe, ọmọ enia, Sọtẹlẹ si ẽmi, sọtẹlẹ, si wi fun ẽmi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ ẽmi, wá lati igun mẹrẹrin, si mí si okú wọnyi, ki nwọn ba le yè.
Bẹ̃ni mo sọtẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi, ẽmi na si wá sinu wọn, nwọn si yè, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn ogun nlanla.
Nigbana li o sọ fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi ni gbogbo ile Israeli: wò o, nwọn wipe, Egungun wa gbẹ, ireti wa si pin: ni ti awa, a ti ke wa kuro.
Nitorina sọtẹlẹ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, ẹnyin enia mi, emi o ṣi ibojì nyin, emi o si mu ki ẹ dide kuro ninu ibojì nyin, emi o si mu nyin wá si ilẹ Israeli.
Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi bá ti ṣí ibojì nyin, ẹnyin enia mi, ti emi bá si mu nyin dide kuro ninu ibojì nyin.
Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, ẹnyin o si yè, emi o si mu nyin joko ni ilẹ ti nyin: nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ ọ, ti o si ti ṣe e, li Oluwa wi.
Ọrọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
Ati iwọ, ọmọ enia, mu igi kan, si kọwe si i lara, Fun Juda, ati fun awọn ọmọ Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀: si mu igi miran, si kọwe si i lara, Fun Josefu, igi Efraimu, ati fun gbogbo ile Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀.
Si dà wọn pọ̀ ṣọkan si igi kan; nwọn o si di ọkan li ọwọ́ rẹ.
Nigbati awọn enia rẹ ba ba ọ sọ̀rọ, wipe, Iwọ kì yio fi idi nkan wọnyi hàn wa?
Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu igi Josefu, ti o wà li ọwọ́ Efraimu, ati awọn ẹya Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀, emi o si mu wọn pẹlu rẹ̀, pẹlu igi Juda, emi o si sọ wọn di igi kan, nwọn o si di ọkan li ọwọ́ mi.
Igi ti iwọ kọwe si lara yio wà li ọwọ́ rẹ, niwaju wọn.
Si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu awọn ọmọ Israeli kuro lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ, emi o si ṣà wọn jọ niha gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ti wọn.
Emi o si sọ wọn di orilẹ-ède kan ni ilẹ lori oke-nla Israeli; ọba kan ni yio si jẹ lori gbogbo wọn: nwọn kì yio si jẹ orilẹ-ède meji mọ, bẹ̃ni a kì yio sọ wọn di ijọba meji mọ rara.
Bẹ̃ni nwọn kì yio fi oriṣa wọn bà ara wọn jẹ mọ, tabi ohun-irira wọn, tabi ohun irekọja wọn: ṣugbọn emi o gbà wọn là kuro ninu gbogbo ibugbe wọn, nibiti nwọn ti dẹṣẹ, emi o si wẹ̀ wọn mọ́: bẹ̃ni nwọn o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.
Dafidi iranṣẹ mi yio si jẹ ọba lori wọn; gbogbo wọn ni yio si ni oluṣọ-agutan kan: nwọn o rìn ninu idajọ mi pẹlu, nwọn o si kiyesi aṣẹ mi, nwọn o si ṣe wọn.
Nwọn o si ma gbe ilẹ ti emi ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi, nibiti awọn baba nyin ti gbe; nwọn o si ma gbe inu rẹ̀, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ ọmọ wọn lailai: Dafidi iranṣẹ mi yio si ma jẹ ọmọ-alade wọn lailai.
Pẹlupẹlu emi o ba wọn dá majẹmu alafia; yio si jẹ majẹmu aiyeraiye pẹlu wọn: emi o si gbe wọn kalẹ, emi o si mu wọn rẹ̀, emi o si gbe ibi mimọ́ mi si ãrin wọn titi aiye.
Agọ mi yio wà pẹlu wọn: nitõtọ, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.
Awọn keferi yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ Israeli di mimọ́, nigbati ibi mimọ́ mi yio wà li ãrin wọn titi aiye.