Ọmọ enia, kini igi ajara fi ju igikigi lọ, tabi ju ẹka ti o wà lãrin igi igbo? A ha le mu igi lara rẹ̀ ṣe iṣẹkiṣẹ? tabi enia le mu ẽkàn lara rẹ̀ lati fi ohunkohun kọ́ sori rẹ̀. Kiyesi i, a jù u sinu iná bi igi, iná si jo ipẹkun rẹ̀ mejeji, ãrin rẹ̀ si jona. O ha yẹ fun iṣẹkiṣẹ bi? Kiyesi i, nigbati o wà li odidi, kò yẹ fun iṣẹ kan: melomelo ni kì yio si yẹ fun iṣẹkiṣẹ, nigbati iná ba ti jo o, ti o si jona? Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi igi ajara lãrin igi igbó, ti mo ti fi fun iná bi igi, bẹ̃ni emi o fi ara Jerusalemu ṣe.
Kà Esek 15
Feti si Esek 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Esek 15:2-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò