Yio si ṣe, bi nwọn kò ba gbà ọ gbọ́, ti nwọn kò si fetisi ohùn iṣẹ-àmi iṣaju, njẹ nwọn o gbà ohùn iṣẹ-àmi ikẹhin gbọ́.
Yio si ṣe, bi nwọn kò ba si gbà àmi mejeji yi gbọ́ pẹlu, ti nwọn kò si fetisi ohùn rẹ, njẹ ki iwọ ki o bù ninu omi odò nì, ki o si dà a si iyangbẹ ilẹ: omi na ti iwọ bù ninu odò yio di ẹ̀jẹ ni iyangbẹ ilẹ.
Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo.
OLUWA si wi fun u pe, Tali o dá ẹnu enia? tabi tali o dá odi, tabi aditi, tabi ariran, tabi afọju? Emi OLUWA ha kọ́?
Njẹ lọ nisisiyi, emi o si pẹlu ẹnu rẹ, emi o si kọ́ ọ li eyiti iwọ o wi.
On si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, rán ẹniti iwọ o rán.
Inu OLUWA si ru si Mose, o si wipe, Aaroni arakunrin rẹ ọmọ Lefi kò ha wà? Emi mọ̀ pe o le sọ̀rọ jọjọ. Ati pẹlu, kiyesi i, o si mbọ̀wá ipade rẹ: nigbati o ba si ri ọ, on o yọ̀ ninu ọkàn rẹ̀.
Iwọ o si sọ̀rọ fun u, iwọ o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu: emi o si pẹlu ẹnu rẹ, ati pẹlu ẹnu rẹ̀, emi o si kọ́ nyin li eyiti ẹnyin o ṣe.
On ni yio si ma ṣe ogbifọ rẹ fun awọn enia: yio si ṣe, on o ma jẹ́ ẹnu fun ọ, iwọ o si ma jẹ́ bi Olọrun fun u.
Iwọ o si mú ọpá yi li ọwọ́ rẹ, eyiti iwọ o ma fi ṣe iṣẹ-àmi.