Eks 4:1-31

Eks 4:1-31 YBCV

MOSE si dahùn o si wipe, Ṣugbọn kiyesi i, nwọn ki yio gbà mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn ki yio fetisi ohùn mi: nitoriti nwọn o wipe, OLUWA kò farahàn ọ. OLUWA si wi fun u pe, Kini wà li ọwọ́ rẹ nì? On si wipe, Ọpá ni. O si wi fun u pe, Sọ ọ si ilẹ. On si sọ ọ si ilẹ, o si di ejò; Mose si sá kuro niwaju rẹ̀. OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ ki o si mú u ni ìru: (On si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si di ọpá si i li ọwọ́:) Ki nwọn ki o le gbàgbọ́ pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o farahàn ọ. OLUWA si tun wi fun u pe, Fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. O si fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀: nigbati o si fà a yọ jade, si kiyesi i, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, o fún bi ẹ̀gbọn owu. O si wipe, Tun fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. (O si tun fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀; o si fà a yọ jade li àiya rẹ̀; si kiyesi i, o si pada bọ̀ bi ẹran ara rẹ̀.) Yio si ṣe, bi nwọn kò ba gbà ọ gbọ́, ti nwọn kò si fetisi ohùn iṣẹ-àmi iṣaju, njẹ nwọn o gbà ohùn iṣẹ-àmi ikẹhin gbọ́. Yio si ṣe, bi nwọn kò ba si gbà àmi mejeji yi gbọ́ pẹlu, ti nwọn kò si fetisi ohùn rẹ, njẹ ki iwọ ki o bù ninu omi odò nì, ki o si dà a si iyangbẹ ilẹ: omi na ti iwọ bù ninu odò yio di ẹ̀jẹ ni iyangbẹ ilẹ. Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo. OLUWA si wi fun u pe, Tali o dá ẹnu enia? tabi tali o dá odi, tabi aditi, tabi ariran, tabi afọju? Emi OLUWA ha kọ́? Njẹ lọ nisisiyi, emi o si pẹlu ẹnu rẹ, emi o si kọ́ ọ li eyiti iwọ o wi. On si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, rán ẹniti iwọ o rán. Inu OLUWA si ru si Mose, o si wipe, Aaroni arakunrin rẹ ọmọ Lefi kò ha wà? Emi mọ̀ pe o le sọ̀rọ jọjọ. Ati pẹlu, kiyesi i, o si mbọ̀wá ipade rẹ: nigbati o ba si ri ọ, on o yọ̀ ninu ọkàn rẹ̀. Iwọ o si sọ̀rọ fun u, iwọ o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu: emi o si pẹlu ẹnu rẹ, ati pẹlu ẹnu rẹ̀, emi o si kọ́ nyin li eyiti ẹnyin o ṣe. On ni yio si ma ṣe ogbifọ rẹ fun awọn enia: yio si ṣe, on o ma jẹ́ ẹnu fun ọ, iwọ o si ma jẹ́ bi Olọrun fun u. Iwọ o si mú ọpá yi li ọwọ́ rẹ, eyiti iwọ o ma fi ṣe iṣẹ-àmi. Mose si lọ, o si pada tọ̀ Jetro ana rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nlọ ki emi si pada tọ̀ awọn arakunrin mi ti o wà ni Egipti, ki emi ki o si wò bi nwọn wà li ãye sibẹ̀. Jetro si wi fun Mose pe, Mã lọ li alafia. OLUWA si wi fun Mose ni Midiani pe, Lọ, pada si Egipti: nitori gbogbo enia ti nwá ẹmi rẹ ti kú tán. Mose si mú aya rẹ̀ ati awọn ọmọ-ọkunrin rẹ̀, o si gbé wọn gùn kẹtẹkẹtẹ kan, o si pada si ilẹ Egipti: Mose si mú ọpá Ọlọrun na li ọwọ́ rẹ̀. OLUWA si wi fun Mose pe, Nigbati iwọ ba dé Egipti, kiyesi i ki iwọ ki o ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu, ti mo filé ọ lọwọ, niwaju Farao, ṣugbọn emi o mu àiya rẹ̀ le, ti ki yio fi jẹ ki awọn enia na ki o lọ. Iwọ o si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA wi, Ọmọ mi ni Israeli, akọ́bi mi: Emi si ti wi fun ọ pe, Jẹ ki ọmọ mi ki o lọ, ki o le ma sìn mi; iwọ si ti kọ̀ lati jẹ ki o lọ: kiyesi i, emi o pa ọmọ rẹ, ani akọ́bi rẹ. O si ṣe li ọ̀na ninu ile-èro, li OLUWA pade rẹ̀, o si nwá ọ̀na lati pa a. Nigbana ni Sippora mú okuta mimú, o si kọ ọmọ rẹ̀ ni ilà abẹ, o si sọ ọ si ẹsẹ̀ Mose, o si wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ fun mi nitõtọ. Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. Nigbana ni Sippora wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ nitori ikọlà na. OLUWA si wi fun Aaroni pe, Lọ si ijù lọ ipade Mose. On si lọ, o si pade rẹ̀ li oke Ọlọrun, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. Mose si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o rán a fun Aaroni, ati gbogbo aṣẹ iṣẹ-àmi ti o fi fun u. Mose ati Aaroni si lọ, nwọn si kó gbogbo àgba awọn ọmọ Israeli jọ: Aaroni si sọ gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA ti sọ fun Mose, o si ṣe iṣẹ-àmi na li oju awọn enia na. Awọn enia na si gbàgbọ́: nigbati nwọn si gbọ́ pe, OLUWA ti bẹ̀ awọn ọmọ Israeli wò, ati pe o si ti ri ipọnju wọn, nigbana ni nwọn tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn.