OLUWA si wi fun Mose pe, Emi ti ri awọn enia yi, si kiyesi i, ọlọrùn lile enia ni: Njẹ nisisiyi jọwọ mi jẹ, ki ibinu mi ki o gbona si wọn, ki emi ki o le pa wọn run: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla. Mose si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, OLUWA, ẽtiṣe ti ibinu rẹ fi gbona si awọn enia rẹ, ti iwọ fi ipá nla ati ọwọ́ agbara rẹ mú lati ilẹ Egipti jade wá? Nitori kini awọn ara Egipti yio ṣe sọ wipe, Nitori ibi li o ṣe mú wọn jade, lati pa wọn lori oke, ati lati run wọn kuro lori ilẹ? Yipada kuro ninu ibinu rẹ ti o muna, ki o si yi ọkàn pada niti ibi yi si awọn enia rẹ. Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Israeli awọn iranṣẹ rẹ, ẹniti iwọ fi ara rẹ bura fun, ti iwọ si wi fun wọn pe, Emi o mu irú-ọmọ nyin bisi i bi irawọ ọrun, ati gbogbo ilẹ na ti mo ti sọ nì, irú-ọmọ nyin li emi o fi fun, nwọn o si jogún rẹ̀ lailai. OLUWA si yi ọkàn pada niti ibi na ti o ti sọ pe on o ṣe si awọn enia rẹ̀.
Kà Eks 32
Feti si Eks 32
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 32:9-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò