Eks 3:7-15

Eks 3:7-15 YBCV

OLUWA si wipe, Nitõtọ emi ti ri ipọnju awọn enia mi ti o wà ni Egipti, mo si gbọ́ igbe wọn nitori awọn akoniṣiṣẹ wọn; nitoriti mo mọ̀ ibanujẹ wọn; Emi si sọkalẹ wa lati gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti, ati lati mú wọn goke ti ilẹ na wá si ilẹ rere ati nla, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin; si ibi ti awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, igbe awọn ọmọ Israeli dé ọdọ mi; emi si ti ri pẹlu, wahala ti awọn ọba Egipti nwahala wọn. Nitorina wá nisisiyi, emi o si rán ọ si Farao, ki iwọ ki o le mú awọn enia mi, awọn ọmọ Israeli, lati Egipti jade wá. Mose si wi fun Ọlọrun pe, Tali emi, ti emi o fi tọ̀ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israeli jade lati Egipti wá? O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi. Mose si wi fun Ọlọrun pe, Kiyesi i, nigbati mo ba dé ọdọ awọn ọmọ Israeli, ti emi o si wi fun wọn pe, Ọlọrun awọn baba nyin li o rán mi si nyin; ti nwọn o si bi mi pe, Orukọ rẹ̀? kili emi o wi fun wọn? Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNITI O WA: o si wipe, Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, EMI NI li o rán mi si nyin. Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Eks 3:7-15