O si wipe, Emi li Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu. Mose si pa oju rẹ̀ mọ́; nitoriti o bẹ̀ru lati bojuwò Ọlọrun. OLUWA si wipe, Nitõtọ emi ti ri ipọnju awọn enia mi ti o wà ni Egipti, mo si gbọ́ igbe wọn nitori awọn akoniṣiṣẹ wọn; nitoriti mo mọ̀ ibanujẹ wọn; Emi si sọkalẹ wa lati gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti, ati lati mú wọn goke ti ilẹ na wá si ilẹ rere ati nla, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin; si ibi ti awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, igbe awọn ọmọ Israeli dé ọdọ mi; emi si ti ri pẹlu, wahala ti awọn ọba Egipti nwahala wọn.
Kà Eks 3
Feti si Eks 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 3:6-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò