Eks 3:14-22

Eks 3:14-22 YBCV

Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNITI O WA: o si wipe, Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, EMI NI li o rán mi si nyin. Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran. Lọ, ki o si kó awọn àgba Israeli jọ, ki o si wi fun wọn pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, ti Isaaki, ati ti Jakobu, li o farahàn mi wipe, Lõtọ ni mo ti bẹ̀ nyin wò, mo si ti ri ohun ti a nṣe si nyin ni Egipti: Emi si ti wipe, Emi o mú nyin goke jade ninu ipọnju Egipti si ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin. Nwọn o si fetisi ohùn rẹ: iwọ o si wá, iwọ ati awọn àgba Israeli, sọdọ ọba Egipti, ẹnyin o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu pade wa: jẹ ki a lọ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki awa ki o le rubọ si OLUWA Ọlọrun wa. Emi si mọ̀ pe ọba Egipti ki yio jẹ ki ẹnyin ki o lọ, ki tilẹ iṣe nipa ọwọ́ agbara. Emi o si nà ọwọ́ mi, emi o si fi iṣẹ-iyanu mi gbogbo kọlù Egipti ti emi o ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin eyinì li on o to jọwọ nyin lọwọ lọ. Emi o si fi ojurere fun awọn enia yi li oju awọn ara Egipti: yio si ṣe, nigbati ẹnyin o lọ, ẹnyin ki yio lọ li ofo: Olukuluku obinrin ni yio si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ, lọwọ aladugbo rẹ̀, ati lọwọ ẹniti o nṣe atipo ninu ile rẹ̀: ẹnyin o si fi wọn si ara awọn ọmọkunrin nyin, ati si ara awọn ọmọbinrin nyin: ẹnyin o si kó ẹrù awọn ara Egipti.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Eks 3:14-22

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa