Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNITI O WA: o si wipe, Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, EMI NI li o rán mi si nyin. Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran. Lọ, ki o si kó awọn àgba Israeli jọ, ki o si wi fun wọn pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, ti Isaaki, ati ti Jakobu, li o farahàn mi wipe, Lõtọ ni mo ti bẹ̀ nyin wò, mo si ti ri ohun ti a nṣe si nyin ni Egipti
Kà Eks 3
Feti si Eks 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 3:14-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò