Njẹ eyi ni iwọ o ma fi rubọ lori pẹpẹ na; ọdọ-agutan meji ọlọdún kan li ojojumọ́ lailai. Ọdọ-agutan kan ni iwọ o fi rubọ li owurọ̀; ati ọdọ-agutan keji ni iwọ o fi rubọ li aṣalẹ: Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin hini oróro ti a gún pòlu; ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ mimu, fun ọdọ-agutan ekini. Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o pa rubọ li aṣalẹ, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi ẹbọ jijẹ owurọ̀, ati gẹgẹ bi ẹbọ mimu rẹ̀, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. Ẹbọ sisun titilai ni yio ṣe lati irandiran nyin li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA: nibiti emi o ma bá nyin pade lati ma bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀.
Kà Eks 29
Feti si Eks 29
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 29:38-42
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò