Eks 2:1-10

Eks 2:1-10 YBCV

ỌKUNRIN kan ara ile Lefi si lọ, o si fẹ́ ọmọbinrin Lefi kan. Obinrin na si yún, o si bi ọmọkunrin kan: nigbati o si ri i pe, o ṣe ọmọ didara, o pa a mọ́ li oṣù mẹta. Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na. Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti yio ṣe ọmọ na. Ọmọbinrin Farao si sọkalẹ wá lati wẹ̀ li odò; awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ si nrìn lọ li ẹba odò na; nigbati o si ri apoti na lãrin koriko odò, o rán ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ kan lati lọ gbé e wá. Nigbati o si ṣi i, o ri ọmọ na; si kiyesi i ọmọde na nsọkun. Inu rẹ̀ si yọ́ si i, o si wipe, Ọkan ninu awọn ọmọ Heberu li eyi. Nigbana li arabinrin rẹ̀ wi fun ọmọbinrin Farao pe, Emi ka lọ ipè alagbatọ kan fun ọ wá ninu awọn obinrin Heberu, ki o tọ́ ọmọ na fun ọ? Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Lọ. Ọmọbinrin na si lọ, o si pè iya ọmọ na wá. Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Gbé ọmọ yi lọ ki o si tọ́ ọ fun mi, emi o si san owo iṣẹ rẹ fun ọ. Obinrin na si gbé ọmọ na lọ, o si tọ́ ọ. Ọmọ na si dàgba, o si mú u tọ̀ ọmọbinrin Farao wá, on si di ọmọ rẹ̀. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Mose, o si wipe, Nitoriti mo fà a jade ninu omi.