Mose si goke tọ̀ Ọlọrun lọ, OLUWA si kọ si i lati oke na wá wipe, Bayi ni ki iwọ ki o sọ fun ile Jakobu, ki o si wi fun awọn ọmọ Israeli pe; Ẹnyin ti ri ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-ìyẹ́ idì, ti mo si mú nyin tọ̀ ara mi wá. Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ́ gbà ohùn mi gbọ́ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ́, nigbana li ẹnyin o jẹ́ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi. Ẹnyin o si ma jẹ́ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ède mimọ́. Wọnyi li ọ̀rọ ti iwọ o sọ fun awọn ọmọ Israeli.
Kà Eks 19
Feti si Eks 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 19:3-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò