Eks 14:10-20

Eks 14:10-20 YBCV

Nigbati Farao si nsunmọtosi, awọn ọmọ Israeli gbé oju soke, si kiyesi i, awọn ara Egipti mbọ̀ lẹhin wọn; ẹ̀ru si bà wọn gidigidi: awọn ọmọ Israeli si kigbe pè OLUWA. Nwọn si wi fun Mose pe, Nitoriti isà kò sí ni Egipti, ki iwọ ṣe mú wa wá lati kú ni ijù? ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃, lati mú wa jade ti Egipti wá? Ọrọ yi ki awa ti sọ fun ọ ni Egipti pe, Jọwọ wa jẹ ki awa ki o ma sìn awọn ara Egipti? O sá san fun wa lati ma sin awọn ara Egipti, jù ki awa kú li aginjù lọ. Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri ìgbala OLUWA, ti yio fihàn nyin li oni: nitori awọn ara Egipti ti ẹnyin ri li oni yi, ẹnyin ki yio si tun ri wọn mọ́ lailai. Nitoriti OLUWA yio jà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pa ẹnu nyin mọ́. OLUWA si wi fun Mose pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkepè mi? sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o tẹ̀ siwaju: Ṣugbọn iwọ gbé ọpá rẹ soke, ki iwọ ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju okun ki o si yà a meji: awọn ọmọ Israeli yio si là ãrin okun na kọja ni iyangbẹ ilẹ. Ati emi kiyesi i, emi o mu àiya awọn ara Egipti le, nwọn o si tẹle wọn: a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori gbogbo ogun rẹ̀, ati lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀. Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba gbà ogo lori Farao, lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀. Angeli Ọlọrun na ti o ṣaju ogun Israeli, o si ṣi lọ ṣẹhin wọn; ọwọ̀n awọsanma si ṣi kuro niwaju wọn, o si duro lẹhin wọn: O si wá si agbedemeji ogun awọn ara Egipti ati ogun Israeli; o si ṣe awọsanma ati òkunkun fun awọn ti ọhún, ṣugbọn o ṣe imọlẹ li oru fun awọn ti ihin: bẹ̃li ekini kò sunmọ ekeji ni gbogbo oru na.