Est 9:23-32

Est 9:23-32 YBCV

Awọn Ju si gbà lati ṣe bi nwọn ti bẹ̀rẹ si iṣe, ati bi Mordekai si ti kọwe si wọn. Pe, Hamani ọmọ Medata, ara Agagi nì, ọta gbogbo awọn Ju ti gbiro lati pa awọn Ju run, o si ti da Puri, eyinì ni ibo, lati pa wọn, ati lati run wọn; Ṣugbọn nigbati Esteri tọ̀ ọba wá, o fi iwe paṣẹ pe, ki ete buburu ti a ti pa si awọn Ju ki o le pada si ori on tikalarẹ̀, ati ki a so ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sori igi. Nitorina ni nwọn ṣe npè ọjọ wọnni ni Purimu bi orukọ Puri. Nitorina gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ inu iwe yi, ati nitori gbogbo eyi ti oju wọn ti ri nitori ọ̀ran yi, ati eyiti o ti ba wọn, Awọn Ju lanà rẹ̀, nwọn si gbà a kanri wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ati fun gbogbo awọn ti o dà ara wọn pọ̀ mọ wọn, pe ki o máṣe yẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọjọ mejeji wọnyi mọ́ gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi akokò wọn ti a yàn lọdọdun. Ati pe, ki nwọn ma ranti ọjọ wọnyi, ki nwọn si ma kiyesi i ni irandiran wọn gbogbo; olukuluku idile, olukuluku ìgberiko, ati olukuluku ilu; ati pe, ki Purimu wọnyi ki o máṣe yẹ̀ larin awọn Ju, tabi ki iranti wọn ki o máṣe parun ninu iru-ọmọ wọn. Nigbana ni Esteri ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Mordekai, ara Juda, fi ọlá gbogbo kọwe, lati fi idi iwe keji ti Purimu yi mulẹ. O si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju, si ẹtadilãdoje ìgberiko ijọba Ahaswerusi, ọ̀rọ alafia ati otitọ. Lati fi idi ọjọ Purimu wọnyi mulẹ, li akokò wọn ti a yàn gẹgẹ bi Mordekai, ara Juda, ati Esteri ayaba ti paṣẹ fun wọn, ati bi nwọn ti pinnu rẹ̀ fun ara wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ọ̀ran ãwẹ ati ẹkún wọn. Aṣẹ Esteri si fi idi ọ̀ran Purimu yi mulẹ; a si kọ ọ sinu iwe.