Njẹ li oṣù kejila, eyini ni oṣù Adari, li ọjọ kẹtala rẹ̀, ti ofin ọba ati aṣẹ rẹ̀ sunmọle lati mu u ṣẹ, li ọjọ ti awọn ọta awọn Ju ti rò pe, awọn o bori wọn, (bi o tilẹ ti jẹ pe, ati yi i pada pe, ki awọn Ju ki o bori awọn ti o korira wọn;)
Awọn Ju kó ara wọn jọ ninu ilu wọn ninu gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, lati gbe ọwọ le iru awọn ti o nwá ifarapa wọn: ẹnikẹni kò si le kò wọn loju; nitori ẹ̀ru wọn bà gbogbo enia.
Gbogbo awọn olori ìgberiko, ati awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati awọn ti nṣe iṣẹ ọba, ràn awọn Ju lọwọ, nitori ẹ̀ru Mordekai bà wọn.
Nitori Mordekai tobi ni ile ọba, okiki rẹ̀ si kàn ja gbogbo ìgberiko: nitori ọkunrin yi Mordekai ntobi siwaju ati siwaju.
Bayi ni awọn Ju a fi idà ṣá gbogbo awọn ọta wọn pa, ni pipa ati piparun, nwọn si ṣe awọn ọta ti o korira wọn bi nwọn ti fẹ.
Ati ni Ṣuṣani ãfin awọn Ju pa ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin run.
Ati Farṣandata, ati Dalfoni, ati Aspata,
Ati Porata, ati Adalia, ati Aridata,
Ati Farmaṣta, ati Arisai, ati Aridai, ati Faisata,
Awọn ọmọ Hamani, ọmọ Medata, mẹwẹwa, ọta awọn Ju ni nwọn pa; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn.
Li ọjọ na a mu iye awọn ti a pa ni Ṣuṣani ãfin wá siwaju ọba.
Ọba si wi fun Esteri ayaba pe, Awọn Ju pa, nwọn si ti pa ẹ̃dẹgbẹta enia run ni Ṣuṣani ãfin, ati awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa: kini nwọn ha ṣe ni gbogbo ìgberiko ọba iyokù? nisisiyi kini ẹbẹ rẹ? a o si fi fun ọ tabi kini iwọ o si tun bère si i? a o si ṣe e.
Nigbana ni Esteri wipe, Bi o ba wù ọba, jẹ ki a fi aṣẹ fun awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani ki nwọn ki o ṣe li ọ̀la pẹlu gẹgẹ bi aṣẹ ti oni, ki a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀ lori igi.
Ọba si paṣẹ pe, ki a ṣe bẹ̃; a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani; a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀.
Nitorina awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹrinla oṣù Adari pẹlu, nwọn si pa ọ̃durun ọkunrin ni Ṣuṣani; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn.
Ṣugbọn awọn Ju miran, ti o wà ni ìgberiko ọba, kó ara wọn jọ, nwọn dide duro lati gbà ẹmi ara wọn là, nwọn si simi kuro lọwọ awọn ọta wọn, nwọn si pa ẹgbã mẹtadilogoji enia o le ẹgbẹrin ninu awọn ọta wọn, ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kan nkan wọn.
Li ọjọ kẹtala oṣù Adari, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀ ni nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati ayọ̀.
Ṣugbọn awọn Ju ti mbẹ ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹtala rẹ̀, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀; ati li ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati inu didùn.
Nitorina awọn Ju ti o wà ni iletò wọnni, ti nwọn ngbe ilu ti kò li odi, nwọn ṣe ọjọ kẹrinla oṣù Adari li ọjọ inu-didùn, ati àse, ati ọjọ rere, ati ọjọ ti olukulùku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀.