Nigbana ni ọba pẹhinda lati inu àgbala ãfin sinu ibiti nwọn ti nmu ọti-waini, Hamani si ṣubu le ibi ìrọgbọkú lori eyi ti Esteri joko; nigbana ni ọba wi pe, yio ha tẹ́ ayaba lọdọ mi ninu ile bi? Bi ọ̀rọ na ti ti ẹnu ọba jade, nwọn bò oju Hamani. Harbona ọkan ninu awọn ìwẹfa si wi niwaju ọba pe, Sa wò o, igi ti o ga ni ãdọta igbọnwọ ti Hamani ti rì nitori Mordekai ti o ti sọ ọ̀rọ rere fun ọba, o wà li oró ni ile Hamani. Ọba si wi pe, Ẹ so o rọ̀ lori rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn so Hamani rọ̀ sori igi ti o ti rì fun Mordekai; ibinu ọba si rọ̀.
Kà Est 7
Feti si Est 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Est 7:8-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò