Est 1:1-12

Est 1:1-12 YBCV

O si ṣe li ọjọ Ahaswerusi, (eyi ni Ahaswerusi ti o jọba lati India, ani titi o fi de Etiopia, lori ẹtadiladoje ìgberiko:) Li ọjọ wọnni, nigbati Ahaswerusi, ọba, joko lori itẹ ijọba rẹ̀, ti o wà ni Ṣuṣani, ãfin. Li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o sè àse kan fun gbogbo awọn ijoye ati awọn iranṣẹ rẹ̀; awọn balogun Persia ati Media, awọn ọlọla, ati awọn olori ìgberiko wọnni wà niwaju rẹ̀: Nigbati o fi ọrọ̀ ijọba rẹ̀ ti o logo, ati ọṣọ iyebiye ọlanla rẹ̀ han lọjọ pipọ̀, ani li ọgọsan ọjọ. Nigbati ọjọ wọnyi si pari, ọba sè àse kan li ọjọ meje fun gbogbo awọn enia ti a ri ni Ṣuṣani ãfin, ati àgba ati ewe ni agbala ọgba ãfin ọba. Nibiti a gbe ta aṣọ àla daradara, aṣọ alaro, ati òféfe, ti a fi okùn ọ̀gbọ daradara, ati elesè aluko dimu mọ oruka fadaka, ati ọwọ̀n okuta marbili: wura ati fadaka ni irọgbọku, ti o wà lori ilẹ ti a fi okuta alabastari, marbili, ilẹkẹ daradara, ati okuta dudu tẹ́. Ninu ago wura li a si nfun wọn mu, (awọn ohun elo na si yatọ si ara wọn) ati ọti-waini ọba li ọ̀pọlọpọ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to. Gẹgẹ bi aṣẹ si ni mimu na; ẹnikẹni kò fi ipa rọ̀ ni: nitori bẹ̃ni ọba ti fi aṣẹ fun gbogbo awọn olori ile rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣe gẹgẹ bi ifẹ olukuluku. Faṣti ayaba sè àse pẹlu fun gbogbo awọn obinrin ni ile ọba ti iṣe ti Ahaswerusi. Li ọjọ keje, nigbati ọti-waini mu inu ọba dùn, o paṣẹ fun Mehumani, Bista, Harbona, Bigta ati Abagta, Ṣetari ati Karkasi, awọn iwẹfa meje ti njiṣẹ niwaju Ahaswerusi ọba. Lati mu Faṣti, ayaba wá siwaju ọba, ti on ti ade ọba, lati fi ẹwà rẹ̀ hàn awọn enia, ati awọn ijoye: nitori arẹwà obinrin ni. Ṣugbọn Faṣti ayaba kọ̀ lati wá nipa aṣẹ ọba lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀: nitorina ni ọba binu gidigidi, ibinu rẹ̀ si gbiná ninu rẹ̀.