Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran ìjọ, ti o si fi ara rẹ̀ fun u; Ki on ki o le sọ ọ di mimọ́ lẹhin ti a ti fi ọ̀rọ wẹ ẹ mọ́ ninu agbada omi, Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rẹ̀ bi ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ́ ati alaini àbuku. Bẹ̃li o tọ́ ki awọn ọkunrin ki o mã fẹràn awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikarawọn. Ẹniti o ba fẹran aya rẹ̀, o fẹran on tikararẹ̀.
Kà Efe 5
Feti si Efe 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 5:25-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò