O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni; Fun aṣepé awọn enia mimọ́ fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi: Titi gbogbo wa yio fi de iṣọkan igbagbọ́ ati ìmọ Ọmọ Ọlọrun, titi a o fi di ọkunrin, titi a o fi de iwọn gigun ẹ̀kún Kristi: Ki awa ki o máṣe jẹ ewe mọ́, ti a nfi gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́ tì siwa tì sẹhin, ti a si fi ngbá kiri, nipa itanjẹ enia, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati múni ṣina; Ṣugbọn ki a mã sọ otitọ ni ifẹ, ki a le mã dàgbasoke ninu rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti iṣe ori, ani Kristi
Kà Efe 4
Feti si Efe 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 4:11-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò