Efe 4:1-32

Efe 4:1-32 YBCV

NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin, Pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutù, pẹlu ipamọra, ẹ mã fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin; Ki ẹ si mã lakaka lati pa iṣọkan Ẹmí mọ́ ni ìdipọ alafia. Ara kan ni mbẹ, ati Ẹmí kan, ani bi a ti pè nyin sinu ireti kan ti ipè nyin; Oluwa kan, igbagbọ́ kan, baptismu kan, Ọlọrun kan ati Baba gbogbo, ẹniti o wà lori gbogbo ati nipa gbogbo ati ninu nyin gbogbo. Ṣugbọn olukuluku wa li a fi ore-ọfẹ fun gẹgẹ bi oṣuwọn ẹ̀bun Kristi. Nitorina o wipe, Nigbati o gòke lọ si ibi giga, o di igbekun ni igbekun, o si fi ẹ̀bun fun enia. (Njẹ niti pe o goke lọ, kili o jẹ, bikoṣepe o kọ́ sọkalẹ pẹlu lọ si iha isalẹ ilẹ? Ẹniti o ti sọkalẹ, on kanna li o si ti goke rekọja gbogbo awọn ọrun, ki o le kún ohun gbogbo.) O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni; Fun aṣepé awọn enia mimọ́ fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi: Titi gbogbo wa yio fi de iṣọkan igbagbọ́ ati ìmọ Ọmọ Ọlọrun, titi a o fi di ọkunrin, titi a o fi de iwọn gigun ẹ̀kún Kristi: Ki awa ki o máṣe jẹ ewe mọ́, ti a nfi gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́ tì siwa tì sẹhin, ti a si fi ngbá kiri, nipa itanjẹ enia, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati múni ṣina; Ṣugbọn ki a mã sọ otitọ ni ifẹ, ki a le mã dàgbasoke ninu rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti iṣe ori, ani Kristi: Lati ọdọ ẹniti ara na ti a nso ṣọkan pọ, ti o si nfi ara mọra, nipa gbogbo orike ipese, (gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku ẹya-ara ni ìwọn tirẹ̀) o nmu ara na bi si i fun idagbasoke on tikararẹ ninu ifẹ. Njẹ eyi ni mo nwi, ti mo si njẹri ninu Oluwa pe, lati isisiyi lọ ki ẹnyin ki o máṣe rìn mọ́, ani gẹgẹ bi awọn Keferi ti nrin ninu ironu asan wọn, Òye awọn ẹniti o ṣòkunkun, awọn ti o si ti di àjeji si ìwa-bi-Ọlọrun nitori aimọ̀ ti mbẹ ninu wọn, nitori lile ọkàn wọn: Awọn ẹniti ọkàn wọn le rekọja, ti nwọn si ti fi ara wọn fun wọ̀bia, lati mã fi iwọra ṣiṣẹ ìwa-ẽri gbogbo. Ṣugbọn a kò fi Kristi kọ́ nyin bẹ̃; Bi o ba ṣe pe nitotọ li ẹ ti gbohùn rẹ̀, ti a si ti kọ́ nyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi otitọ ti mbẹ ninu Jesu: Pe, niti iwa nyin atijọ, ki ẹnyin ki o bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ, eyiti o dibajẹ gẹgẹ bi ifẹkufẹ ẹ̀tan; Ki ẹ si di titun ni ẹmi inu nyin; Ki ẹ si gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a da nipa ti Ọlọrun li ododo ati li iwa mimọ́ otitọ́. Nitorina ẹ fi eke ṣiṣe silẹ, ki olukuluku nyin ki o mã ba ọmọnikeji rẹ̀ sọ otitọ, nitori ẹ̀ya-ara ọmọnikeji wa li awa iṣe. Ẹ binu; ẹ má si ṣe ṣẹ̀: ẹ máṣe jẹ ki õrùn wọ̀ bá ibinu nyin: Bẹni ki ẹ má ṣe fi àye fun Èṣu. Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini. Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́. Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande. Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn: Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.

Verse Images for Efe 4:1-32

Efe 4:1-32 - NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin,
Pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutù, pẹlu ipamọra, ẹ mã fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin;
Ki ẹ si mã lakaka lati pa iṣọkan Ẹmí mọ́ ni ìdipọ alafia.
Ara kan ni mbẹ, ati Ẹmí kan, ani bi a ti pè nyin sinu ireti kan ti ipè nyin;
Oluwa kan, igbagbọ́ kan, baptismu kan,
Ọlọrun kan ati Baba gbogbo, ẹniti o wà lori gbogbo ati nipa gbogbo ati ninu nyin gbogbo.
Ṣugbọn olukuluku wa li a fi ore-ọfẹ fun gẹgẹ bi oṣuwọn ẹ̀bun Kristi.
Nitorina o wipe, Nigbati o gòke lọ si ibi giga, o di igbekun ni igbekun, o si fi ẹ̀bun fun enia.
(Njẹ niti pe o goke lọ, kili o jẹ, bikoṣepe o kọ́ sọkalẹ pẹlu lọ si iha isalẹ ilẹ?
Ẹniti o ti sọkalẹ, on kanna li o si ti goke rekọja gbogbo awọn ọrun, ki o le kún ohun gbogbo.)
O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni;
Fun aṣepé awọn enia mimọ́ fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi:
Titi gbogbo wa yio fi de iṣọkan igbagbọ́ ati ìmọ Ọmọ Ọlọrun, titi a o fi di ọkunrin, titi a o fi de iwọn gigun ẹ̀kún Kristi:
Ki awa ki o máṣe jẹ ewe mọ́, ti a nfi gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́ tì siwa tì sẹhin, ti a si fi ngbá kiri, nipa itanjẹ enia, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati múni ṣina;
Ṣugbọn ki a mã sọ otitọ ni ifẹ, ki a le mã dàgbasoke ninu rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti iṣe ori, ani Kristi:
Lati ọdọ ẹniti ara na ti a nso ṣọkan pọ, ti o si nfi ara mọra, nipa gbogbo orike ipese, (gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku ẹya-ara ni ìwọn tirẹ̀) o nmu ara na bi si i fun idagbasoke on tikararẹ ninu ifẹ.

Njẹ eyi ni mo nwi, ti mo si njẹri ninu Oluwa pe, lati isisiyi lọ ki ẹnyin ki o máṣe rìn mọ́, ani gẹgẹ bi awọn Keferi ti nrin ninu ironu asan wọn,
Òye awọn ẹniti o ṣòkunkun, awọn ti o si ti di àjeji si ìwa-bi-Ọlọrun nitori aimọ̀ ti mbẹ ninu wọn, nitori lile ọkàn wọn:
Awọn ẹniti ọkàn wọn le rekọja, ti nwọn si ti fi ara wọn fun wọ̀bia, lati mã fi iwọra ṣiṣẹ ìwa-ẽri gbogbo.
Ṣugbọn a kò fi Kristi kọ́ nyin bẹ̃;
Bi o ba ṣe pe nitotọ li ẹ ti gbohùn rẹ̀, ti a si ti kọ́ nyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi otitọ ti mbẹ ninu Jesu:
Pe, niti iwa nyin atijọ, ki ẹnyin ki o bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ, eyiti o dibajẹ gẹgẹ bi ifẹkufẹ ẹ̀tan;
Ki ẹ si di titun ni ẹmi inu nyin;
Ki ẹ si gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a da nipa ti Ọlọrun li ododo ati li iwa mimọ́ otitọ́.

Nitorina ẹ fi eke ṣiṣe silẹ, ki olukuluku nyin ki o mã ba ọmọnikeji rẹ̀ sọ otitọ, nitori ẹ̀ya-ara ọmọnikeji wa li awa iṣe.
Ẹ binu; ẹ má si ṣe ṣẹ̀: ẹ máṣe jẹ ki õrùn wọ̀ bá ibinu nyin:
Bẹni ki ẹ má ṣe fi àye fun Èṣu.
Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini.
Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́.
Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.
Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn:
Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.Efe 4:1-32 - NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin,

Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Efe 4:1-32

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa