Ninu ẹniti awa ni igboiya, ati ọ̀na pẹlu igbẹkẹle nipa igbagbọ́ wa ninu rẹ̀. Nitorina mo bẹ̀ nyin ki ãrẹ̀ ki o máṣe mu nyin ni gbogbo wahalà mi nitori nyin, ti iṣe ogo nyin. Nitori idi eyi ni mo ṣe nfi ẽkun mi kunlẹ fun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Orukọ ẹniti a fi npè gbogbo idile ti mbẹ li ọrun ati li aiye, Ki on ki o le fifun nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ ogo rẹ̀, ki a le fi agbara rẹ̀ mú nyin li okun nipa Ẹmí rẹ̀ niti ẹni inu; Ki Kristi ki o le mã gbé inu ọkàn nyin nipa igbagbọ; pe bi ẹ ti nfi gbongbo mulẹ, ti ẹ si nfi ẹsẹ mulẹ ninu ifẹ, Ki ẹnyin ki o le li agbara lati mọ̀ pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́, kini ìbú, ati gigùn, ati jijìn, ati giga na jẹ, Ati lati mọ ifẹ Kristi ti o ta ìmọ yọ, ki a le fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọrun kun nyin.
Kà Efe 3
Feti si Efe 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 3:12-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò