Efe 3:1-13

Efe 3:1-13 YBCV

NITORI eyina, emi Paulu, ondè Jesu Kristi nitori ẹnyin Keferi, Bi ẹnyin ba ti gbọ ti iṣẹ iriju ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun mi fun nyin: Bi o ti ṣepe nipa ifihan li o ti fi ohun ijinlẹ nì hàn fun mi, (gẹgẹ bi mo ti kọ ṣaju li ọrọ diẹ, Nigbati ẹnyin ba kà a, nipa eyi ti ẹnyin ó fi le mọ oye mi ninu ijinlẹ Kristi,) Eyiti a kò ti fihàn awọn ọmọ enia rí ni irandiran miran, bi a ti fi wọn hàn nisisiyi fun awọn aposteli rẹ̀ mimọ́ ati awọn woli nipa Ẹmí; Pe, awọn Keferi jẹ àjumọjogun ati ẹya-ara kanna, ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere: Iranṣẹ eyiti a fi mi ṣe gẹgẹ bi ẹ̀bun ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀. Fun emi ti o kere ju ẹniti o kere julọ ninu gbogbo awọn enia mimọ́, li a fi ore-ọfẹ yi fun, lati wasu awamáridi ọrọ̀ Kristi fun awọn Keferi; Ati lati mu ki gbogbo enia ri kini iṣẹ-iriju ohun ijinlẹ na jasi, eyiti a ti fi pamọ́ lati aiyebaiye ninu Ọlọrun, ẹniti o dá ohun gbogbo nipa Jesu Kristi: Ki a ba le fi ọ̀pọlọpọ onirũru ọgbọ́n Ọlọrun hàn nisisiyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ, Gẹgẹ bi ipinnu ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa: Ninu ẹniti awa ni igboiya, ati ọ̀na pẹlu igbẹkẹle nipa igbagbọ́ wa ninu rẹ̀. Nitorina mo bẹ̀ nyin ki ãrẹ̀ ki o máṣe mu nyin ni gbogbo wahalà mi nitori nyin, ti iṣe ogo nyin.