Ṣugbọn nisisiyi ninu Kristi Jesu ẹnyin ti o ti jìna réré nigba atijọ rí li a mu sunmọ tosi, nipa ẹ̀jẹ Kristi. Nitori on ni alafia wa, ẹniti o ti ṣe mejeji li ọ̀kan, ti o si ti wó ogiri ìkélé nì ti mbẹ lãrin; O si ti fi opin si ọta nì ninu ara rẹ̀, ani si ofin aṣẹ wọnni ti mbẹ ninu ilana; ki o le fi awọn mejeji dá ẹni titun kan ninu ara rẹ̀, ki o si ṣe ilaja, Ati ki o le mu awọn mejeji ba Ọlọrun làja ninu ara kan nipa agbelebu; o si ti pa iṣọta na kú nipa rẹ̀: O si ti wá, o si ti wasu alafia fun ẹnyin ti o jìna réré, ati fun awọn ti o sunmọ tosi: Nitori nipa rẹ̀ li awa mejeji ti ni ọ̀na nipa Ẹmí kan sọdọ Baba. Njẹ nitorina ẹnyin kì iṣe alejò ati atipo mọ́, ṣugbọn àjumọ jẹ ọlọ̀tọ pẹlu awọn enia mimọ́, ati awọn ará ile Ọlọrun; A si ngbé nyin ró lori ipilẹ awọn aposteli, ati awọn woli, Jesu Kristi tikararẹ̀ jẹ pàtaki okuta igun ile; Ninu ẹniti gbogbo ile na, ti a nkọ ṣọkan pọ, ndagbà soke ni tẹmpili mimọ́ ninu Oluwa: Ninu ẹniti a ngbé nyin ró pọ pẹlu fun ibujoko Ọlọrun ninu Ẹmí.
Kà Efe 2
Feti si Efe 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 2:13-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò