Nitorina ẹ ranti pe, nigba atijọ ri, ẹnyin ti ẹ ti jẹ Keferi nipa ti ara, ti awọn ti a npè ni Akọla ti a fi ọwọ ṣe li ara npè li Alaikọla, Pe li akokò na ẹnyin wà laini Kristi, ẹ jẹ ajeji si anfani awọn ọlọtọ Israeli, ati alejo si awọn majẹmu ileri nì, laini ireti, ati laini Ọlọrun li aiye: Ṣugbọn nisisiyi ninu Kristi Jesu ẹnyin ti o ti jìna réré nigba atijọ rí li a mu sunmọ tosi, nipa ẹ̀jẹ Kristi. Nitori on ni alafia wa, ẹniti o ti ṣe mejeji li ọ̀kan, ti o si ti wó ogiri ìkélé nì ti mbẹ lãrin; O si ti fi opin si ọta nì ninu ara rẹ̀, ani si ofin aṣẹ wọnni ti mbẹ ninu ilana; ki o le fi awọn mejeji dá ẹni titun kan ninu ara rẹ̀, ki o si ṣe ilaja
Kà Efe 2
Feti si Efe 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 2:11-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò