ẸNYIN li a si ti sọ di àye, nigbati ẹnyin ti kú nitori irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin, Ninu eyiti ẹnyin ti nrin rí gẹgẹ bi ipa ti aiye yi, gẹgẹ bi alaṣẹ agbara oju ọrun, ẹmí ti nṣiṣẹ nisisiyi ninu awọn ọmọ alaigbọran: Ninu awọn ẹniti gbogbo wa pẹlu ti wà rí ninu ifẹkufẹ ara wa, a nmu ifẹ ara ati ti inu ṣẹ; ati nipa ẹda awa si ti jẹ ọmọ ibinu, gẹgẹ bi awọn iyoku pẹlu. Ṣugbọn Ọlọrun, ẹniti iṣe ọlọrọ̀ li ãnu, nitori ifẹ nla rẹ̀ ti o fi fẹ wa, Nigbati awa tilẹ ti kú nitori irekọja wa, o sọ wa di ãye pẹlu Kristi (ore-ọfẹ li a ti fi gba nyin là).
Kà Efe 2
Feti si Efe 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 2:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò