Oni 6:1-12

Oni 6:1-12 YBCV

IBI kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, o si ṣọpọ lãrin awọn ọmọ enia. Ẹniti Ọlọrun fi ọrọ̀, ọlà ati ọlá fun, ti kò si si nkan ti o si kù fun ọkàn rẹ̀ ninu ohun gbogbo ti o fẹ, ṣugbọn ti Ọlọrun kò fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn awọn ajeji enia li o njẹ ẹ: asan li eyi, àrun buburu si ni. Bi ọkunrin kan bi ọgọrun ọmọ, ti o si wà li ọdun pupọ, tobẹ̃ ti ọjọ ọdun rẹ̀ pọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò si kún fun ohun didara, ati pẹlu ti a kò si sinkú rẹ̀; mo ni, ọmọ iṣẹnu san jù u lọ. Nitoripe lasan li o wá, o si lọ li òkunkun, òkunkun li a o si fi bo orukọ rẹ̀ mọlẹ. Pẹlupẹlu on kò ri õrùn kò mọ ohun kan: eyi ni isimi jù ekeji lọ. Ani bi o tilẹ wà ni ẹgbẹrun ọdun lẹrin-meji, ṣugbọn kò ri rere: ibikanna ki gbogbo wọn ha nrè? Gbogbo lãla enia ni fun ẹnu rẹ̀, ṣugbọn a kò ti itẹ adùn ọkàn rẹ̀ lọrun. Nitoripe ère kili ọlọgbọ́n ni jù aṣiwère lọ? kini talaka ni ti o mọ̀ bi a ti rin niwaju awọn alãye? Eyiti oju ri san jù irokakiri ifẹ lọ; asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo. Eyi ti o wà, a ti da orukọ rẹ̀ ri, a si ti mọ̀ ọ pe, enia ni: bẹ̃ni kò le ba ẹniti o lagbara jù u lọ jà. Kiyesi i ohun pupọ li o wà ti nmu asan bi si i, ère kili enia ni? Nitoripe tali o mọ̀ ohun ti o dara fun enia li aiye yi, ni iye ọjọ asan rẹ̀ ti nlọ bi ojiji? nitoripe tali o le sọ fun enia li ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀ labẹ õrùn?