Oni 5:8-20

Oni 5:8-20 YBCV

Bi iwọ ba ri inilara awọn olupọnju, ati ifi agbara yi idajọ ati otitọ pada ni igberiko, máṣe jẹ ki ẹnu ki o yà ọ si ọ̀ran na: nitoripe ẹniti o ga jù nṣọ ẹniti o ga, ati ẹni-giga-julọ wà lori wọn. Pẹlupẹlu ère ilẹ ni fun gbogbo enia: a si nsìn ọba tikalarẹ pãpa lati inu oko wa. Ẹniti o ba fẹ fadaka, fadaka kì yio tẹ́ ẹ lọrun; bẹ̃li ẹniti o fẹ ọrọ̀ kì yio tẹ́ ẹ lọrun: asan li eyi pẹlu. Nigbati ẹrù ba npọ̀ si i, awọn ti o si njẹ ẹ a ma pọ̀ si i: ore ki tilẹ ni fun ẹniti o ni i bikoṣepe ki nwọn ki o ma fi oju wọn wò o? Didùn ni orun oniṣẹ, iba jẹ onjẹ diẹ tabi pupọ: ṣugbọn itẹlọrun ọlọrọ̀ kì ijẹ, ki o sùn. Ibi buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, eyini ni pe, ọrọ̀ ti a pamọ́ fun ifarapa awọn ti o ni i. Nitori ọrọ̀ wọnni a ṣegbe nipa iṣẹ buburu; bi o si bi ọmọkunrin kan, kò ni nkan lọwọ rẹ̀. Bi o ti ti inu iya rẹ̀ jade wá, ihoho ni yio si tun pada lọ bi o ti wá, kì yio si mu nkan ninu lãla rẹ̀, ti iba mu lọ lọwọ rẹ̀. Ibi buburu li eyi pẹlu, pe li ọ̀na gbogbo, bi o ti wá, bẹ̃ni yio si lọ: ère ki si ni fun ẹniti nṣe lãla fun afẹfẹ? Li ọjọ rẹ̀ gbogbo pẹlu, o njẹun li òkunkun, o si ni ibinujẹ pupọ ati àrun ati irora rẹ̀. Kiyesi eyi ti mo ri: o dara o si yẹ fun enia, ki o jẹ, ki o si mu, ki o si ma jẹ alafia ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn, ni iye ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, ti Ọlọrun fi fun u: nitori eyi ni ipin tirẹ̀. Bi Ọlọrun ba fi ọrọ̀ fun ẹnikẹni, ti o si fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀: ati lati mu ipin rẹ̀, ati lati yọ̀ ninu lãla rẹ eyi; pẹlu ẹ̀bun Ọlọrun ni. Nitoriti kì yio ranti ọjọ aiye rẹ̀ pọju; nitoriti Ọlọrun da a lohùn ninu ayọ̀ ọkàn rẹ̀.