Oni 3:1-17

Oni 3:1-17 YBCV

OLUKULÙKU ohun li akoko wà fun, ati ìgba fun iṣẹ gbogbo labẹ ọrun. Ìgba bibini, ati ìgba kikú, ìgba gbigbin ati ìgba kika ohun ti a gbin; Ìgba pipa ati ìgba imularada; ìgba wiwo lulẹ ati ìgba kikọ; Ìgba sisọkun ati ìgba rirẹrín; ìgba ṣiṣọ̀fọ ati igba jijo; Ìgba kikó okuta danu, ati ìgba kiko okuta jọ; ìgba fifọwọkoni mọra, ati ìgba fifasẹhin ni fifọwọkoni mọra; Ìgba wiwari, ati ìgba sísọnu: ìgba pipamọ́ ati ìgba ṣiṣa tì; Ìgba fifaya, ati ìgba rirán; ìgba didakẹ, ati ìgba fifọhùn; Ìgba fifẹ, ati ìgba kikorira; ìgba ogun, ati ìgba alafia. Ere kili ẹniti nṣiṣẹ ni ninu eyiti o nṣe lãla? Mo ti ri ìṣẹ́ ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ enia lati ma ṣíṣẹ ninu rẹ̀. O ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgba tirẹ̀; pẹlupẹlu o fi aiyeraiye si wọn li aiya, bẹ̃li ẹnikan kò le ridi iṣẹ na ti Ọlọrun nṣe lati ipilẹṣẹ titi de opin. Emi mọ̀ pe kò si rere ninu wọn, bikoṣe ki enia ki o ma yọ̀, ki o si ma ṣe rere li aiya rẹ̀. Ati pẹlu ki olukulùku enia ki o ma jẹ ki o si ma mu, ki o si ma jadùn gbogbo lãla rẹ̀, ẹ̀bun Ọlọrun ni. Emi mọ̀ pe ohunkohun ti Ọlọrun ṣe yio wà lailai: a kò le fi ohun kan kún u, bẹ̃li a kò le mu ohun kan kuro ninu rẹ̀; Ọlọrun si ṣe eyi ki enia ki o le ma bẹ̀ru rẹ̀. Ohun ti o ti wà ri mbẹ nisisiyi, ati eyi ti yio si wà, o ti wà na; Ọlọrun si bère eyi ti o ti kọja lọ. Ati pẹlupẹlu mo ri ibi idajọ labẹ õrùn pe ìwa buburu mbẹ nibẹ; ati ni ibi ododo, pe aiṣedẽde mbẹ nibẹ. Mo wi li aiya mi pe, Ọlọrun yio ṣe idajọ olododo ati enia buburu: nitoripe ìgba kan mbẹ fun ipinnu ati fun iṣẹ gbogbo.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa