Deu 5:6-22

Deu 5:6-22 YBCV

Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá. Iwọ kò gbọdọ ní ọlọrun miran pẹlu mi. Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworán apẹrẹ kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti mbẹ ni ilẹ nisalẹ, tabi ti mbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ: Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitoripe emi OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, ati lara iran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi. Emi a si ma ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si pa ofin mi mọ́. Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ li asan: nitoriti OLUWA ki yio mu ẹniti o pè orukọ rẹ̀ li asan bi alailẹṣẹ lọrùn. Kiyesi ọjọ́-isimi lati yà a simimọ́, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ. Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo: Ṣugbọn ọjọ́ keje li ọjọ́-isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ, ati ohunọ̀sin rẹ kan, ati alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ; ki ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ki o le simi gẹgẹ bi iwọ. Si ranti pe iwọ ti ṣe iranṣẹ ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ibẹ̀ jade wá nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa: nitorina li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe paṣẹ fun ọ lati pa ọjọ́-isimi mọ́. Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ, ati ki o le dara fun ọ, ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. Iwọ kò gbọdọ pania. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jale. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹri-eké si ẹnikeji rẹ. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, oko rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ. Ọ̀rọ wọnyi ni OLUWA sọ fun gbogbo ijọ nyin lori òke lati ãrin iná, awọsanma, ati lati inu òkunkun biribiri wá, pẹlu ohùn nla: kò si fi kún u mọ́. O si kọ wọn sara walã okuta meji, o si fi wọn fun mi.