Deu 4
4
Mose Rọ Àwọn Ọmọ Israẹli Pé kí Wọn Máa Gbọ́ràn
1NJẸ nisisiyi Israeli, fetisi ìlana ati idajọ, ti emi nkọ́ nyin, lati ṣe wọn; ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ si lọ igba ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin fi fun nyin.
2Ẹ kò gbọdọ fikún ọ̀rọ na ti mo palaṣẹ fun nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀, ki ẹnyin ki o le pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin.
3Oju nyin ti ri ohun ti OLUWA ṣe nitori Baali-peori: nitoripe gbogbo awọn ọkunrin ti o tẹlé Baali-peori lẹhin, OLUWA Ọlọrun rẹ ti run wọn kuro lãrin rẹ.
4Ṣugbọn ẹnyin ti o faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gbogbo nyin mbẹ lãye li oni.
5Wò o, emi ti kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, bi OLUWA Ọlọrun mi ti paṣẹ fun mi, pe ki ẹnyin ki o le ma ṣe bẹ̃ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.
6Nitorina ẹ pa wọn mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; nitoripe eyi li ọgbọ́n nyin ati oye nyin li oju awọn orilẹ-ède, ti yio gbọ́ gbogbo ìlana wọnyi, ti yio si wipe, Ọlọgbọ́n ati amoye enia nitõtọ ni orilẹ-ède nla yi.
7Nitori orilẹ-ède nla wo li o wà, ti o ní Ọlọrun sunmọ wọn to, bi OLUWA Ọlọrun wa ti ri ninu ohun gbogbo ti awa kepè e si?
8Ati orilẹ-ède nla wo li o si wà, ti o ní ìlana ati idajọ ti iṣe ododo to bi gbogbo ofin yi, ti mo fi siwaju nyin li oni?
9Kìki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ;
10Li ọjọ́ ti iwọ duro niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu, nigbati OLUWA wi fun mi pe, Pe awọn enia yi jọ fun mi, emi o si mu wọn gbọ́ ọ̀rọ mi, ki nwọn ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru mi li ọjọ́ gbogbo ti nwọn o wà lori ilẹ, ati ki nwọn ki o le ma kọ́ awọn ọmọ wọn.
11Ẹnyin si sunmọtosi, ẹ si duro nisalẹ òke nì; òke na si njòna dé agbedemeji ọrun, pẹlu òkunkun, ati awọsanma, ati òkunkun biribiri.
12OLUWA si sọ̀rọ si nyin lati ãrin iná na wá: ẹnyin gbọ́ ohùn ọ̀rọ na, ṣugbọn ẹ kò ri apẹrẹ kan; kìki ohùn li ẹnyin gbọ́.
13O si sọ majẹmu rẹ̀ fun nyin, ti o palaṣẹ fun nyin lati ṣe, ani ofin mẹwa nì; o si kọ wọn sara walã okuta meji.
14OLUWA si paṣẹ fun mi ni ìgba na lati kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.
Ìkìlọ̀ nípa Ìbọ̀rìṣà
15Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesara nyin gidigidi, nitoripe ẹnyin kò ri apẹrẹ kan li ọjọ́ ti OLUWA bá nyin sọ̀rọ ni Horebu lati ãrin iná wá:
16Ki ẹnyin ki o má ba bà ara nyin jẹ́, ki ẹ má si lọ ṣe ere gbigbẹ, apẹrẹ ohunkohun, aworán akọ tabi abo.
17Aworán ẹrankẹran ti mbẹ lori ilẹ, aworán ẹiyẹkẹiyẹ ti nfò li oju-ọrun.
18Aworán ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, aworán ẹjakẹja ti mbẹ ninu omi nisalẹ ilẹ:
19Ati ki iwọ ki o má ba gbé oju rẹ soke ọrun, nigbati iwọ ba si ri õrùn, ati oṣupa, ati irawọ, ani gbogbo ogun ọrun, ki a má ba sún ọ lọ ibọ wọn, ki o si ma sìn wọn, eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun gbogbo orilẹ-ède labẹ ọrun gbogbo.
20Ṣugbọn OLUWA ti gbà nyin, o si mú nyin lati ileru irin, lati Egipti jade wá, lati ma jẹ́ enia iní fun u, bi ẹnyin ti ri li oni yi.
21OLUWA si binu si mi nitori nyin, o si bura pe, emi ki yio gòke Jordani, ati pe emi ki yio wọ̀ inu ilẹ rere nì, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni ilẹ-iní.
22Ṣugbọn emi o kú ni ilẹ yi, emi ki yio gòke odò Jordani: ṣugbọn ẹnyin o gòke ẹnyin o si gbà ilẹ rere na.
23Ẹ ma ṣọra nyin, ki ẹnyin má ba gbagbé majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti o ti bá nyin dá, ki ẹnyin má ba lọ ṣe ere finfin fun ara nyin, tabi aworán ohunkohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti kọ̀ fun ọ.
24Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ ajonirun iná ni, Ọlọrun owú.
25Nigbati iwọ ba bi ọmọ, ati ọmọ ọmọ, ti ẹ ba si pẹ ni ilẹ na, ti ẹ si bà ara nyin jẹ́, ti ẹ si ṣe ere finfin, tabi aworán ohunkohun, ti ẹ si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA Ọlọrun rẹ lati mu u binu:
26Mo pè ọrun ati aiye jẹri si nyin li oni, pe lọ́gan li ẹnyin o run kuro patapata ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a; ẹnyin ki yio lò ọjọ́ nyin pẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin o si run patapata.
27OLUWA yio si tú nyin ká ninu awọn orilẹ-ède, diẹ ni ẹnyin o si kù ni iye ninu awọn orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio darí nyin si.
28Nibẹ̀ li ẹnyin o si ma sìn oriṣa, iṣẹ ọwọ́ enia, igi ati okuta, ti kò riran, ti kò si gbọran, ti kò jẹun, ti kò si gbõrun.
29Ṣugbọn bi iwọ ba wá OLUWA Ọlọrun rẹ lati ibẹ̀ lọ, iwọ o ri i, bi iwọ ba fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ wá a.
30Nigbati iwọ ba mbẹ ninu ipọnju, ti nkan gbogbo wọnyi ba si bá ọ, nikẹhin ọjọ́, bi iwọ ba yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́:
31Nitoripe Ọlọrun alãnu ni OLUWA Ọlọrun rẹ; on ki yio kọ̀ ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio run ọ, bẹ̃ni ki yio gbagbé majẹmu awọn baba rẹ, ti o ti bura fun wọn.
32Njẹ bère nisisiyi niti ọjọ́ igbãni, ti o ti mbẹ ṣaju rẹ, lati ọjọ́ ti Ọlọrun ti dá enia sori ilẹ, ki o si bère lati ìha ọrun kini dé ìha keji, bi irú nkan bi ohun nla yi wà rí, tabi bi a gburó irú rẹ̀ rí?
33Awọn enia kan ha gbọ́ ohùn Ọlọrun rí ki o ma bá wọn sọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi iwọ ti gbọ́, ti o si wà lãye?
34Tabi Ọlọrun ha dán a wò rí lati lọ mú orilẹ-ède kan fun ara rẹ̀ lati ãrin orilẹ-ède miran wá, nipa idanwò, nipa àmi, ati nipa iṣẹ-iyanu, ati nipa ogun, ati nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa, ati nipa ẹ̀ru nla, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ṣe fun nyin ni Egipti ni oju nyin?
35Iwọ li a fihàn, ki iwọ ki o le mọ̀ pe OLUWA on li Ọlọrun; kò sí ẹlomiran lẹhin rẹ̀.
36O mu ọ gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ọrun wá, ki o le kọ́ ọ: ati lori ilẹ aiye o fi iná nla rẹ̀ hàn ọ; iwọ si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ lati ãrin iná wá.
37Ati nitoriti o fẹ́ awọn baba rẹ, nitorina li o ṣe yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, o si fi agbara nla rẹ̀ mú ọ lati Egipti jade wá li oju rẹ̀;
38Lati lé awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju rẹ, ti o tobi, ti o si lagbara jù ọ lọ, lati mú ọ wọle, lati fi ilẹ wọn fun ọ ni iní, bi o ti ri li oni yi.
39Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ li oni, ki o si rò li ọkàn rẹ pe, OLUWA on li Ọlọrun loke ọrun, ati lori ilẹ nisalẹ: kò sí ẹlomiran.
40Nitorina ki iwọ ki o pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati ofin rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ lori ilẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lailai.
Àwọn Ìlú Ààbò Tí Ó Wà ní Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani
41Nigbana ni Mose yà ilu mẹta sọ̀tọ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn.
42Ki apania ki o le ma sá sibẹ̀, ti o ba ṣì ẹnikeji rẹ̀ pa, ti kò si korira rẹ̀ ni ìgba atijọ rí; ati pe bi o ba sá si ọkan ninu ilu wọnyi ki o le là:
43Beseri ni ijù, ni ilẹ pẹtẹlẹ̀, ti awọn ọmọ Reubeni; ati Ramotu ni Gileadi, ti awọn ọmọ Gadi; ati Golani ni Baṣani, ti awọn ọmọ Manasse.
Àlàyé lórí Òfin Ọlọrun Tí Mose Fẹ́ fún Wọn
44Eyi li ofin na ti Mose filelẹ niwaju awọn ọmọ Israeli:
45Wọnyi li ẹrí, ati ìlana, ati idajọ, ti Mose filelẹ fun awọn ọmọ Israeli, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá;
46Ni ìha ẹ̀bá Jordani, ni afonifoji ti o kọjusi Beti-peori, ni ilẹ Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni, ẹniti Mose ati awọn ọmọ Israeli kọlù, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá:
47Nwọn si gbà ilẹ rẹ̀, ati ilẹ Ogu ọba Baṣani, awọn ọba Amori mejeji ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn;
48Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ani dé òke Sioni (ti iṣe Hermoni,)
49Ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ nì, ni ìha ẹ̀bá Jordani ni ìha ìla-õrùn, ani dé okun pẹtẹlẹ̀ nì, nisalẹ awọn orisun Pisga.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 4: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.