Deu 34
34
Ikú Mose
1MOSE si gòke lati pẹtẹlẹ̀ Moabu lọ si òke Nebo, si ori Pisga, ti o dojukọ Jeriko. OLUWA si fi gbogbo ilẹ Gileadi dé Dani hàn a;
2Ati gbogbo Naftali, ati ilẹ Efraimu, ati ti Manasse, ati gbogbo ilẹ Juda, dé okun ìwọ-õrùn;
3Ati gusù, ati pẹtẹlẹ̀ afonifoji Jeriko, ilu ọlọpẹ dé Soari.
4OLUWA si wi fun u pe, Eyi ni ilẹ ti mo bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Emi o fi i fun irú-ọmọ rẹ: emi mu ọ fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ ki yio rekọja lọ sibẹ̀.
5Bẹ̃ni Mose iranṣẹ OLUWA kú nibẹ̀ ni ilẹ Moabu, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA.
6O si sin i ninu afonifoji ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Beti-peori; ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o mọ̀ iboji rẹ̀ titi di oni-oloni.
7Mose si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún nigbati o kú: oju rẹ̀ kò ṣe baìbai, bẹ̃li agbara rẹ̀ kò dinku.
8Awọn ọmọ Israeli si sọkun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu li ọgbọ̀n ọjọ́: bẹ̃li ọjọ́ ẹkún ati ọ̀fọ Mose pari.
9Joṣua ọmọ Nuni si kún fun ẹmi ọgbọ́n; nitoripe Mose ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori: awọn ọmọ Israeli si gbà tirẹ̀ gbọ́, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
10Wolĩ kan kò si hù mọ́ ni Israeli bi Mose, ẹniti OLUWA mọ̀ li ojukoju,
11Ni gbogbo iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, ti OLUWA rán a lati ṣe ni ilẹ Egipti, si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀;
12Ati ni gbogbo ọwọ́ agbara, ati ni gbogbo ẹ̀ru nla ti Mose fihàn li oju gbogbo Israeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 34: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.