Deu 32:28-44

Deu 32:28-44 YBCV

Nitori orilẹ-ède ti kò ní ìmọ ni nwọn, bẹ̃ni kò sí òye ninu wọn. Ibaṣepe nwọn gbọ́n, ki òye eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn! Ẹnikan iba ti ṣe lé ẹgbẹrun, ti ẹni meji iba si lé ẹgbãrun sá, bikoṣepe bi Apata wọn ti tà wọn, ti OLUWA si fi wọn tọrẹ? Nitoripe apata wọn kò dabi Apata wa, ani awọn ọtá wa tikalawọn ni nṣe onidajọ. Nitoripe igi-àjara wọn, ti igi-àjara Sodomu ni, ati ti igbẹ́ Gomorra: eso-àjara wọn li eso-àjara orõro, ìdi wọn korò: Ọti-waini wọn iwọ ti dragoni ni, ati oró mimu ti pamọlẹ̀. Eyi ki a tojọ sọdọ mi ni ile iṣura, ti a si fi èdidi dì ninu iṣura mi? Ti emi ni igbẹsan, ati ẹsan, li akokò ti ẹsẹ̀ wọn yio yọ́: nitoriti ọjọ́ idamu wọn sunmọtosi, ohun ti o si mbọ̀ wa bá wọn nyára wá. Nitoripe OLUWA yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si kãnu awọn iranṣẹ rẹ̀; nigbati o ba ri pe agbara wọn lọ tán, ti kò si sí ẹnikan ti a sé mọ́, tabi ti o kù. On o si wipe, Nibo li oriṣa wọn gbé wà, apata ti nwọn gbẹkẹle: Ti o ti jẹ ọrá ẹbọ wọn, ti o ti mu ọti-waini ẹbọ ohunmimu wọn? jẹ ki nwọn dide ki nwọn si ràn nyin lọwọ, ki nwọn ṣe àbo nyin. Wò o nisisiyi pe Emi, ani Emi ni, kò si sí ọlọrun pẹlu mi: mo pa, mo si sọ di ãye; mo ṣalọgbẹ, mo si mu jiná; kò si sí ẹnikan ti o le gbà silẹ li ọwọ́ mi. Nitoripe mo gbé ọwọ́ mi soke ọrun, mo si wipe, Bi Emi ti wà titilai. Bi mo ba si pọ́n idà didan mi, ti mo ba si fi ọwọ́ mi lé idajọ; emi o san ẹsan fun awọn ọtá mi, emi o radi i fun awọn ti o korira mi. Emi o mu ọfà mi rin fun ẹ̀jẹ, idà mi o si jẹ ẹran; ninu ẹ̀jẹ ẹni pipa ati ti igbekun, lati ori awọn aṣaju ọtá. Ẹ ma yọ̀, ẹnyin orilẹ-ède, pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on o gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀, yio si gbẹsan lara awọn ọtá rẹ̀, yio si ṣètutu fun ilẹ rẹ̀, ati fun awọn enia rẹ̀. Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi li etí awọn enia na, on, ati Hoṣea ọmọ Nuni.