Deu 32:1-27

Deu 32:1-27 YBCV

FETISILẸ, ẹnyin ọrun, emi o si sọ̀rọ; si gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi, iwọ aiye: Ẹkọ́ mi yio ma kán bi ojò ohùn mi yio ma sẹ̀ bi ìri; bi òjo winiwini sara eweko titun, ati bi ọ̀wara òjo sara ewebẹ̀: Nitoriti emi o kokikí orukọ OLUWA kiri: ẹ fi ọlá fun Ọlọrun wa. Apata na, pipé ni iṣẹ rẹ̀; nitoripe idajọ ni gbogbo ọ̀na rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alàiṣegbe, ododo ati otitọ li on. Nwọn ti bà ara wọn jẹ́ lọdọ rẹ̀, nwọn ki iṣe ọmọ rẹ̀, àbuku wọn ni; iran arekereke ati wiwọ́ ni nwọn. Bayi li ẹnyin o ha san ẹsan fun OLUWA, ẹnyin aṣiwere enia ati alaigbọn? On ha kọ́ ni baba rẹ ti o rà ọ? on li o dá ọ, on li o si fi ẹsẹ̀ rẹ mulẹ? Ranti ọjọ́ igbãni, ronu ọdún iraniran: bi baba rẹ lere yio si fihàn ọ; bi awọn àgba rẹ, nwọn o si sọ fun ọ. Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli. Nitoripe ipín ti OLUWA li awọn enia rẹ̀; Jakobu ni ipín iní rẹ̀. O ri i ni ilẹ aṣalẹ̀, ati ni aginjù nibiti ẹranko nke; o yi i ká, o tọju rẹ̀, o pa a mọ́ bi ẹyin oju rẹ̀: Bi idì ti irú itẹ́ rẹ̀, ti iràbaba sori ọmọ rẹ̀, ti inà iyẹ́-apa rẹ̀, ti igbé wọn, ti ima gbé wọn lọ lori iyẹ́-apa rẹ̀: Bẹ̃ni OLUWA nikan ṣamọ̀na rẹ̀, kò si sí oriṣa pẹlu rẹ̀. O mu u gùn ibi giga aiye, ki o le ma jẹ eso oko; o si jẹ ki o mu oyin lati inu apata wá, ati oróro lati inu okuta akọ wá; Ori-amọ́ malu, ati warà agutan, pẹlu ọrá ọdọ-agutan, ati àgbo irú ti Baṣani, ati ewurẹ, ti on ti ọrá iwe alikama; iwọ si mu ẹ̀jẹ eso-àjara, ani ọti-waini. Ṣugbọn Jeṣuruni sanra tán, o si tapa: iwọ sanra tán, iwọ kì tan, ọrá bò ọ tán: nigbana li o kọ̀ Ọlọrun ti o dá a, o si gàn Apata ìgbala rẹ̀. Nwọn fi oriṣa mu u jowú, ohun irira ni nwọn fi mu u binu. Nwọn rubọ si iwin-buburu ti ki iṣe Ọlọrun, si oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, si oriṣa ti o hù ni titun, ti awọn baba nyin kò bẹ̀ru. Apata ti o bi ọ ni iwọ kò ranti, iwọ si ti gbagbé Ọlọrun ti o dá ọ. OLUWA si ri i, o si korira wọn, nitori ìwa-imunibinu awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati ti awọn ọmọbinrin rẹ̀. O si wipe, Emi o pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, emi o si ma wò bi igbẹhin wọn yio ti ri; nitori iran alagídi ni nwọn, awọn ọmọ ninu ẹniti kò sí igbagbọ. Nwọn ti fi ohun ti ki iṣe Ọlọrun mu mi jowú; nwọn si fi ohun asan wọn mu mi binu: emi o si fi awọn ti ki iṣe enia mu wọn jowú; emi o si fi aṣiwere orilẹ-ède mu wọn binu. Nitoripe iná kan ràn ninu ibinu mi, yio si jó dé ipò-okú ni isalẹ, yio si run aiye pẹlu asunkún rẹ̀, yio si tinabọ ipilẹ awọn okenla. Emi o kó ohun buburu jọ lé wọn lori; emi o si lò ọfà mi tán si wọn lara: Ebi yio mu wọn gbẹ, oru gbigbona li a o fi run wọn, ati iparun kikorò; emi o si rán ehín ẹranko si wọn, pẹlu oró ohun ti nrakò ninu erupẹ. Idà li ode, ati ipàiya ninu iyẹwu, ni yio run ati ọmọkunrin ati wundia, ọmọ ẹnu-ọmu, ati ọkunrin arugbo elewu irun pẹlu. Mo wipe, Emi o tu wọn ká patapata, emi o si mu iranti wọn dá kuro ninu awọn enia: Bikoṣepe bi mo ti bẹ̀ru ibinu ọtá, ki awọn ọtá wọn ki o má ba ṣe alaimọ̀, ati ki nwọn ki o má ba wipe, Ọwọ́ wa leke ni, ki isi ṣe OLUWA li o ṣe gbogbo eyi.