Deu 31:1-13

Deu 31:1-13 YBCV

MOSE si lọ, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli. O si wi fun wọn pe, Emi di ẹni ọgọfa ọdún li oni; emi kò le ma jade ki nsi ma wọle mọ́: OLUWA si ti wi fun mi pe, Iwọ ki yio gòke Jordani yi mọ́. OLUWA Ọlọrun rẹ, on ni yio rekọja ṣaju rẹ, on ni yio si run orilẹ-ède wọnyi kuro niwaju rẹ, iwọ o si gbà wọn: ati Joṣua, on ni yio gòke ṣaju rẹ, bi OLUWA ti wi. OLUWA yio si ṣe si wọn bi o ti ṣe si Sihoni ati si Ogu, ọba awọn Amori, ati si ilẹ wọn; awọn ẹniti o run. OLUWA yio si fi wọn tọrẹ niwaju nyin, ki ẹnyin ki o le fi wọn ṣe gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ ti mo pa fun nyin. Ẹ ṣe giri ki ẹ si mu àiya le, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya wọn: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ, on li o mbá ọ lọ; on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ. Mose si pè Joṣua, o si wi fun u li oju gbogbo Israeli pe, Ṣe giri ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio bá awọn enia yi lọ si ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba wọn, lati fi fun wọn; iwọ o si mu wọn gbà a. Ati OLUWA on li o nlọ ṣaju rẹ; on ni yio pẹlu rẹ, on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ: máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ. Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli. Mose si paṣẹ fun wọn, wipe, Li opin ọdún meje meje li akokò ọdún idasilẹ, ni ajọ agọ́. Nigbati gbogbo Israeli ba wá farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti on o gbé yàn, ki iwọ ki o kà ofin yi niwaju gbogbo Israeli li etí wọn. Kó awọn enia na jọ, awọn ọkunrin ati awọn obinrin ati awọn ọmọde, ati alejò rẹ ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki nwọn ki o le gbọ́, ati ki nwọn ki o le kọ ati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ati ki nwọn ki o ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi; Ati ki awọn ọmọ wọn, ti kò mọ̀, ki o le gbọ́, ki nwọn si kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngóke Jordani lọ lati gbà a.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa