YIO si ṣe, nigbati gbogbo nkan wọnyi ba dé bá ọ, ibukún ati egún, ti mo filelẹ niwaju rẹ, ti iwọ o ba si ranti ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si, Ti iwọ ba si yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo; Nigbana ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio yi oko-ẹrú rẹ pada, yio si ṣãnu fun ọ, yio si pada, yio si kó ọ jọ kuro ninu gbogbo orilẹ-ède wọnni nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si. Bi a ba si lé ẹni rẹ kan lọ si ìha opin ọrun, lati ibẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio kó ọ jọ, lati ibẹ̀ ni yio si mú ọ wá
Kà Deu 30
Feti si Deu 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 30:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò