YIO si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ̀ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ: Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ. Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko. Ibukún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ati irú ohunọ̀sin rẹ, ati ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ. Ibukún ni fun agbọ̀n rẹ ati fun ọpọ́n-ipò-àkara rẹ. Ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba jade. OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọ̀na kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọ̀na meje. OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé; on o si busi i fun ọ ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
Kà Deu 28
Feti si Deu 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 28:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò