Deu 27
27
Ìlànà nípa Kíkọ Òfin Ọlọrun Sára Òkúta
1MOSE pẹlu awọn àgba Israeli si paṣẹ fun awọn enia na wipe, Ẹ ma pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni.
2Yio si ṣe li ọjọ́ ti ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o si kó okuta nla jọ, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
3Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara wọn, nigbati iwọ ba rekọja; ki iwọ ki o le wọ̀ inu ilẹ na lọ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ, ti ṣe ileri fun ọ.
4Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani tán, ẹnyin o kó okuta wọnyi jọ, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, li òke Ebali, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
5Nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pẹpẹ okuta kan: iwọ kò gbọdọ fi ohun-èlo irin kàn wọn.
6Okuta aigbẹ́ ni ki iwọ ki o fi mọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA Ọlọrun rẹ:
7Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ alafia, ki iwọ ki o si jẹun nibẹ̀; ki iwọ ki o ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ.
8Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara okuta wọnyi, ki o hàn gbangba.
9Mose ati awọn alufa awọn ọmọ Lefi si sọ fun gbogbo Israeli pe, Israeli, dakẹ, ki o si gbọ́; li oni ni iwọ di enia OLUWA Ọlọrun rẹ.
10Nitorina ki iwọ ki o gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, ki o si ma ṣe aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.
Àwọn Ègún fún Àìgbọràn
11Mose si paṣẹ fun awọn enia na li ọjọ́ na, wipe,
12Awọn wọnyi ni ki o duro lori òke Gerisimu, lati ma sure fun awọn enia na, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani; Simeoni, ati Lefi, ati Juda, ati Issakari, ati Josefu, ati Benjamini:
13Awọn wọnyi ni yio si duro lori òke Ebali lati gegún; Reubeni, Gadi, ati Aṣeri, ati Sebuluni, Dani, ati Naftali.
14Awọn ọmọ Lefi yio si dahùn, nwọn o si wi fun gbogbo awọn ọkunrin Israeli li ohùn rara pe,
15Egún ni fun ọkunrin na ti o yá ere gbigbẹ́ tabi didà, irira si OLUWA, iṣẹ ọwọ́ oniṣọnà, ti o si gbé e kalẹ ni ìkọ̀kọ̀. Gbogbo enia yio si dahùn wipe, Amin.
16Egún ni fun ẹniti kò fi baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀ pè. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
17Egún ni fun ẹniti o ṣí àla ẹnikeji rẹ̀ kuro. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
18Egún ni fun ẹniti o ṣì afọju li ọ̀na. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
19Egún ni fun ẹniti o nyi idajọ alejò po, ati ti alainibaba, ati ti opó. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
20Egún ni fun ẹniti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ̀: nitoriti o tú aṣọ baba rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
21Egún ni fun ẹniti o bá ẹranko dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
22Egún ni fun ẹniti o bá arabinrin rẹ̀ dàpọ, ti iṣe ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
23Egún ni fun ẹniti o bá iya-aya rẹ̀ dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
24Egún ni fun ẹniti o lù ẹnikeji rẹ̀ ni ìkọkọ. Gbogbo enia ni yio si wipe, Amin.
25Egún ni fun ẹniti o gbà ọrẹ lati pa alaiṣẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
26Egún ni fun ẹniti kò duro si gbogbo ọ̀rọ ofin yi lati ṣe wọn. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 27: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.