Deu 25:17-19

Deu 25:17-19 YBCV

Ranti ohun ti Amaleki ṣe si ọ li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti ilẹ Egipti jade wá; Bi o ti pade rẹ li ọ̀na, ti o si kọlù awọn ti o kẹhin rẹ, ani gbogbo awọn ti o ṣe alailera lẹhin rẹ, nigbati ãrẹ mú ọ tán, ti agara si dá ọ; ti on kò si bẹ̀ru Ọlọrun. Nitorina yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fun ọ ni isimi lọwọ gbogbo awọn ọtá rẹ yi ọ ká kiri, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati ní i, ki iwọ ki o si pa iranti Amaleki rẹ́ kuro labẹ ọrun; iwọ kò gbọdọ gbagbé.