Bi ọkunrin kan ba lí ọmọkunrin kan ti o ṣe agídi ati alaigbọran, ti kò gbà ohùn baba rẹ̀ gbọ́, tabi ohùn iya rẹ̀, ati ti nwọn nà a, ti kò si fẹ́ gbà tiwọn gbọ́: Nigbana ni ki baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ki o mú u, ki nwọn ki o si fà a jade tọ̀ awọn àgba ilu rẹ̀ wá ati si ibode ibujoko rẹ̀; Ki nwọn ki o si wi fun awọn àgba ilu rẹ̀ pe, Ọmọ wa yi, alagídi ati alaigbọran ni, on kò fẹ́ gbọ́ ohùn wa; ọjẹun ati ọmuti ni. Ki gbogbo awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-ibi kuro lãrin nyin; gbogbo Israeli a si gbọ́, nwọn a si bẹ̀ru.
Kà Deu 21
Feti si Deu 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 21:18-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò