Deu 20
20
Ọ̀rọ̀ nípa Ogun
1NIGBATI iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti iwọ si ri ẹṣin, ati kẹkẹ́-ogun, ati awọn enia ti o pọ̀ jù ọ, máṣe bẹ̀ru wọn: nitori OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá.
2Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba sunmọ ogun na, ki alufa ki o sunmọtosi, ki o si sọ̀rọ fun awọn enia.
3Ki o si wi fun wọn pe, Gbọ́, Israeli, li oni ẹnyin sunmọ ogun si awọn ọtá nyin: ẹ máṣe jẹ ki àiya nyin ki o ṣojo, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe warìri, bẹ̃ni ẹ má si ṣe fòya nitori wọn;
4Nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ni mbá nyin lọ, lati bá awọn ọtá nyin jà fun nyin, lati gbà nyin là.
5Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia, pe, Ọkunrin wo li o kọ ile titun, ti kò ti ikó si i? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba kó si i.
6Ati ọkunrin wo li o gbìn ọgbà-àjara, ti kò si ti ijẹ ninu rẹ̀? jẹ ki on pẹlu ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba jẹ ẹ.
7Ati ọkunrin wo li o fẹ́ iyawo, ti kò ti igbé e? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba gbé e.
8Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia na si i, ki nwọn ki o si wipe, Ọkunrin wo li o wà ti o bẹ̀ru ti o si nṣojo? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki àiya awọn arakunrin rẹ̀ ki o má ba ṣojo pẹlu bi àiya tirẹ̀.
9Yio si ṣe, nigbati awọn olori-ogun ba pari ọ̀rọ sisọ fun awọn enia tán, ki nwọn ki o si fi awọn balogun jẹ lori awọn enia na.
10Nigbati iwọ ba sunmọ ilu kan lati bá a jà, nigbana ni ki iwọ ki o fi alafia lọ̀ ọ.
11Yio si ṣe, bi o ba da ọ lohùn alafia, ti o si ṣilẹkun silẹ fun ọ, njẹ yio ṣe, gbogbo awọn enia ti a ba bá ninu rẹ̀, nwọn o si ma jẹ́ ọlọsin fun ọ, nwọn o si ma sìn ọ.
12Bi kò ba si fẹ́ bá ọ ṣe alafia, ṣugbọn bi o ba fẹ́ bá ọ jà, njẹ ki iwọ ki o dótì i:
13Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi i lé ọ lọwọ, ki iwọ ki o si fi oju idà pa gbogbo ọkunrin ti mbẹ ninu rẹ̀:
14Ṣugbọn awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ ati ohun-ọ̀sin, ati ohun gbogbo ti mbẹ ni ilu na, ani gbogbo ikogun rẹ̀, ni ki iwọ ki o kó fun ara rẹ; ki iwọ ki o si ma jẹ ikogun awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
15Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo ilu ti o jìna rére si ọ, ti ki iṣe ninu ilu awọn orilẹ-ède wọnyi.
16Ṣugbọn ninu ilu awọn enia wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki iwọ ki o máṣe da ohun kan si ti o nmí:
17Ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn run patapata; awọn ọmọ Hitti, ati awọn Amori, awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ:
18Ki nwọn ki o má ba kọ́ nyin lati ma ṣe bi gbogbo iṣẹ-irira wọn, ti nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; ẹnyin a si ṣẹ̀ bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin.
19Nigbati iwọ ba dótì ilu kan pẹ titi, lati bá a jà lati kó o, ki iwọ ki o máṣe run igi tutù rẹ̀ ni yiyọ ãke tì wọn; nitoripe iwọ le ma jẹ ninu wọn, iwọ kò si gbọdọ ke wọn lulẹ; nitori igi igbẹ́ ha ṣe enia bi, ti iwọ o ma dòtí i?
20Kìki igi ti iwọ mọ̀ pe nwọn ki iṣe igi jijẹ, on ni ki iwọ ki o run, ki o si ke lulẹ; ki iwọ ki o si sọ agbàra tì ilu na ti mbá ọ jà, titi a o fi ṣẹ́ ẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 20: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.